1 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá wí pé:
2 “Ọmọ ènìyàn, báwo ni igi àjàrà ṣe dára ju igi mìíràn lọ tàbí jù ẹ̀ka àjàrà tó wà láàrin igi yòókù nínú igbó?
3 Ǹjẹ́ a wa lè mú igi lára rẹ̀ ṣe nǹkan ti o wúlò bí? Tàbí kí ènìyàn fi ṣe èèkàn tí yóò fi nǹkan kọ́?
4 Lẹ́yìn èyí, ṣe a jù ú sínú iná gẹ́gẹ́ bí epo ìdáná, gbogbo igun rẹ̀ jóná pẹ̀lú àárin rẹ, ṣé o wà le wúlò fún nǹkan kan mọ́?
5 Tí kò bá wúlò fún nǹkankan nígbà tó wà lódidi, báwo ni yóò ṣe wá wúlò nígbà tíná ti jó o, tó sì dúdú nítorí èéfín?
6 “Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Bí mo ṣe sọ igi àjàrà tó wà láàrin àwọn igi inú igbó yóòkù di igi ìdáná, bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò ṣe ṣe gbogbo ènìyàn tó ń gbé Jérúsálẹ́mù.
7 Èmi yóò dojúkọ wọ́n. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ti jáde kúrò nínú iná kan síbẹ̀ iná mìíràn yóò pàpà jó wọn. Nígbà tí mo bá sì dojúkọ wọ́n, ẹ ó sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.
8 Èmi yóò sọ ilé náà di ahoro nítorí ìwà àìsòótọ́ wọn, ni Olúwa Ọlọ́run wí.”