Ísíkẹ́lì 11 BMY

Ìdájọ́ Lórí Àwọn Àgbà Ísírẹ́lì

1 Ẹ̀mí sì gbé mi sókè, ó mú mi lọ sí ẹnu ọ̀nà ilé Olúwa èyí tó dojú kọ ìlà oòrùn. Ní àbáwọlé ẹnu ọ̀nà yìí ni àwọn ọkùnrin mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n (25) wá, mo rí Jáásáníà ọmọ Àsúrì àti Pélátíà ọmọ Bénáyà, tí wọ́n jẹ́ aláṣẹ àwọn ènìyàn.

2 Olúwa sì sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, àwọn ọkùnrin yìí ló ń pète ibi, wọ́n sì ń gba ìmọ̀ràn búburú kalẹ̀ nínú ìlú.

3 Wọ́n ní, ‘kò ha tí ì tó àsìkò láti kọ́lé? Ìlú yìí ni ìkòkò ìdáná, àwa sì ni ẹran’.

4 Nítorí náà sọtẹ́lẹ̀ nípa wọn; ọmọ ènìyàn, sọ tẹ́lẹ̀.”

5 Ẹ̀mí Olúwa sì bà lé mi, ó sì wí pé, “Sọ̀rọ̀!” Báyìí ni Olúwa wí, Ohun tí ẹ-ń sọ níyìí, ilé Ísírẹ́lì, mo mọ ohun tó wà lọ́kàn yín.

6 Bí ẹ ṣe ń pànìyàn tún ti pọ̀ síi nínú ìlú, òkú sì ti kún gbogbo ojú pópó.

7 “Torí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí, àwọn òkú tí ẹ pa sáàrin yín ni ẹran, ìlú yìí sì ni ìkòkò ìdáná ṣùgbọ́n n ó le yín jáde níbẹ̀.

8 Ẹ bẹ̀rù idà, n ó sì mú idà wá sórí yín, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí.

9 N ó lé yín jáde kúrò ní ìlú yìí, n ó sì fà yín lé àlejò lọ́wọ́, n ó sì mú ìdájọ́ ṣẹ lé yín lórí.

10 Nípa idà ni ẹ ó ṣubú, n ó sì ṣe ìdájọ́ yín ní àwọn ààlà ìlú Ísírẹ́lì. Nígbà náà lẹ ó mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.

11 Ìlú yìí kò ní i jẹ́ ìkòkò ìdáná, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin náà kò sì ní jẹ́ ẹran nínú rẹ̀; N ó ṣe ìdájọ́ yín ní àwọn ààlà ìlú Ísírẹ́lì.

12 Ẹ̀yin ó sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa, nítorí pé ẹ̀yin kò tẹ̀lé àṣẹ mi ẹ kò sì pa òfin mi mọ́, ṣùgbọ́n ẹ ti hùwà gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìgbàgbọ́ orílẹ̀ èdè tó yí yín ká.”

13 Bí mo ṣe ń sọtẹ́lẹ̀ lọ́wọ́, Pélátíà ọmọ Bénáyà kú. Mo sì dojúbolẹ̀, mo sì kígbe sókè pé, “Áà! Olúwa, Ọlọ́run! Ṣé o fẹ́ pa ìyókù Ísírẹ́lì run pátapáta ni?”

14 Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá:

15 “Ọmọ ènìyàn, àwọn arákùnrin rẹ, àní àwọn ará rẹ, àwọn ọkùnrin nínú ìbátan rẹ, àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì pátapáta, ni àwọn ará Jérúsálẹ́mù ti wí fún pé, ‘Ẹ jìnnà sí Olúwa, àwa ni a fi ilẹ̀ yìí fún yín ní ìní.’

Ìlérí Pé Ísírẹ́lì Yóò Padà

16 “Nítorí náà, sọ fún àwọn tó wà ní ìgbèkùn pé, ‘Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti fọ́n wọn káàkiri orílẹ̀ èdè, síbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, n ó jẹ́ ibi mímọ́ fún wọn níbi tí wọ́n lọ.’

17 “Nítorí náà, sọ pé: ‘Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Èmi yóò kó wọn jọ kúrò láàrin àwọn orílẹ̀ èdè tí mo fọ́n wọn ká sí, Èmi yóò sì fún wọn ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì padà.’

18 “Wọn yóò padà síbẹ̀, wọn ó sì mú gbogbo àwòrán ìríra rẹ̀ àti ìbọ̀rìṣà kúrò.

19 N ó fún wọn ní ọ̀kan kan; èmi yóò sì fi ẹ̀mí tuntun sínú wọn; N ó mú ọkàn òkúta kúrò lára wọn, n ó sì fún wọn ní ọkàn tó rọ̀ bí ara ẹran.

20 Kí wọn le tẹ̀lé àṣẹ mi, kí wọn sì le pa òfin mi mọ́. Wọ́n yóò jẹ́ ènìyàn mi, Èmi náà yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn.

21 Ṣùgbọ́n fún àwọn tí wọ́n ń fi gbogbo ọkàn wọn sin àwọn àwòrán ìríra àti àwọn òrìṣà, Èmi yóò mú ẹ̀san ohun tí wọ́n ṣe wá sórí wọn bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Ọlọ́run wí.”

22 Àwọn kérúbù sì gbé ìyẹ́ wọn sókè pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn ògo Ọlọ́run Ísírẹ́lì sì wà lókè orí wọn.

23 Ògo Olúwa sì gòkè lọ kúrò láàrin ìlú, ó sì dúró lórí òkè tó wà ní ìlà oòrùn ìlú náà.

24 Ẹ̀mí gbé mi sókè, ó sì mú mi lójú ìran lọ bá àwọn ìgbèkùn Bábílónì. Ìran tí mo rí sì parí,

25 Mo sì sọ gbogbo ohun tí Olúwa fihàn mí fún àwọn tó wà ní Ìgbèkùn.