14 “Bí ọkùnrin yìí bá bímọ, tó sì rí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ti baba rẹ ń ṣẹ̀ yìí, tó sì bẹ̀rù, ti kò ṣe bẹ́ẹ̀:
15 “Tí kò jẹun lójúbọ lórí òkè gígatàbí kò gbójú sókè sí àwọnòrìṣà ilé Ísírẹ́lì, tí kò sì báiyàwó aládùúgbò rẹ̀ jẹ́
16 tí kò ni ẹnikẹ́ni lára,tí kò hùwà ibití kò gba èlé tàbí kò fipá jalèṣùgbọ́n tí ó ń fún ẹni tébi ń pa lóúnjẹ,tó sì fi aṣọ bo àwọn oníhòhò.
17 Ó ń yọ ọwọ́ rẹ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀,kò sì gba èlé tàbí èlé tó pọ̀jù,ó ń pa òfin mi mọ́,ó sì ń tẹ̀lé àwọn àsẹ mi.Kò ní kú fún ẹ̀ṣẹ̀ baba rẹ̀, nítòótọ́ ní yóò yè!
18 Ṣùgbọ́n baba rẹ̀ ni yóò kú fún ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀, nítorí pé ó jẹ́ arẹ́nijẹ, ó jalè arákùnrin rẹ, ó ṣe ohun tí kò dára láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀.
19 “Síbẹ̀, ẹ tún ń bèèrè pé, ‘Kí ló dé ti ọmọ kò ní í ru ẹ̀bi baba rẹ̀?’ Níwọ̀n ìgbà tí ọmọ ti ṣe ohun tó tọ́, tó sì yẹ, tó sì ti kíyè sí ara láti pa gbogbo àṣẹ mi mọ́, nítòótọ́ ni pé yóò yè.
20 Ọkàn tí ó bá sẹ̀ ní yóò kú. Ọmọ kò ní í ru ẹ̀bi baba rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni baba náà kò ní i ru ẹ̀bi ọmọ rẹ̀. Ìwà rere ènìyàn rere yóò wà lórí rẹ̀, ìwà búburú ti ènìyàn búburu náà la ó kà síi lọ́rùn.