19 “Síbẹ̀, ẹ tún ń bèèrè pé, ‘Kí ló dé ti ọmọ kò ní í ru ẹ̀bi baba rẹ̀?’ Níwọ̀n ìgbà tí ọmọ ti ṣe ohun tó tọ́, tó sì yẹ, tó sì ti kíyè sí ara láti pa gbogbo àṣẹ mi mọ́, nítòótọ́ ni pé yóò yè.
20 Ọkàn tí ó bá sẹ̀ ní yóò kú. Ọmọ kò ní í ru ẹ̀bi baba rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni baba náà kò ní i ru ẹ̀bi ọmọ rẹ̀. Ìwà rere ènìyàn rere yóò wà lórí rẹ̀, ìwà búburú ti ènìyàn búburu náà la ó kà síi lọ́rùn.
21 “Ṣùgbọ́n bí ènìyàn búburú bá yípadà kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tó ti dá, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í pa àsẹ mi mọ́, tó sì ń ṣe ohun tó tọ́ àti ohun tó yẹ, nítòótọ́ ni yóò yè, kò sì ní kú.
22 A kò sì ní rántí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tó ti dá tẹ́lẹ̀ láti kàá sí lọ́rùn nítorí tí ìwà òdodo rẹ tó fihàn, yóò yè
23 Ǹjẹ́ se mo ni inú dídùn si ikú ènìyàn búburú bí í? Ní Olúwa wí, dípò èyí inú mi kò ha ni i dùn nígbà tó ba yípadà kúrò ni àwọn ọ̀nà búburú rẹ̀ tó sì yè?
24 “Ṣùgbọ́n bí ènìyàn rere bá yípadà kúrò ni ọ̀nà òdodo rẹ̀ tó sì ń dẹ́sẹ̀, tó sì tún n ṣe àwọn ohun ìríra tí ènìyàn búburú ń ṣe, yóò wa yè bí? A kò ni i rántí ọ̀kan kan nínú ìwà rere rẹ̀ mọ́, nítorí ó ti jẹ̀bi ìwà àrékérekè àti ẹ̀ṣẹ̀ tó dá, yóò sì kú.
25 “Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ tún sọ pe, ‘Olúwa kò ṣe é da kò tọ́.’ Gbọ́, ilé Ísírẹ́lì: se ọ̀nà mi ni kò tọ́? Kì í wa ṣé pé ọ̀nà ti yín gan-an ni kò tọ́?