4 Nítorí pé èmi ló ní gbogbo ọkàn, ọkàn baba tèmi bẹ́ẹ̀ ni ọkàn ọmọ pàápá jẹ tèmi, ọkàn tó bá sẹ̀ ní yóò kú.
5 “Bí ọkùnrin Olódodo kan bá wà,tó ń ṣe ohun tó tọ́, tó sì yẹ
6 tí kò bá wọn jẹun lórí òkè gíga,tí kò gbójú rẹ̀ sókè sí àwọnòrìṣà ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ti kò sì báobìnrin aládùúgbò rẹ̀ jẹ́ tàbí kí ósùn ti obìnrin ni àsìkò èérí rẹ̀.
7 Kò ní ẹnikẹ́ni lára,ó sì sanwó fún onígbésè rẹ̀ gẹ́gẹ́bó ṣe ṣe ìlérí fún un, kò fi ipájalè ṣùgbọ́n ó fún ẹni tí ebi ńpa ní oúnjẹ, tí ó sì fi ẹ̀wù wọàwọn tí ó wà ní ìhòòhò.
8 Kò yá ènìyàn ni owó ẹ̀dá tàbí kò gba èlétó pọ̀jù. Ó yọ ọwọ́ rẹ̀ kúrò nínúìwà ẹ̀ṣẹ̀, ó sì ń ṣe ìdájọ́ àìṣègbèláàrin ọkùnrin kan àti èkejì rẹ̀.
9 Tí ó ń tẹ̀lé àsẹ mi,tí ó sì ń pa òfin mi mọ́ lotítọ́ àti lódodo.Ó jẹ́ olódodo,yóò yè nítòótọ́,ní Olúwa Ọlọ́run wí.
10 “Bí ó bá bi ọmọkùnrin, oniwà ipá, tó ń jalè, tó tún ń pànìyàn tó sì ń ṣe gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí sí arákùnrin rẹ̀