7 Kò ní ẹnikẹ́ni lára,ó sì sanwó fún onígbésè rẹ̀ gẹ́gẹ́bó ṣe ṣe ìlérí fún un, kò fi ipájalè ṣùgbọ́n ó fún ẹni tí ebi ńpa ní oúnjẹ, tí ó sì fi ẹ̀wù wọàwọn tí ó wà ní ìhòòhò.
8 Kò yá ènìyàn ni owó ẹ̀dá tàbí kò gba èlétó pọ̀jù. Ó yọ ọwọ́ rẹ̀ kúrò nínúìwà ẹ̀ṣẹ̀, ó sì ń ṣe ìdájọ́ àìṣègbèláàrin ọkùnrin kan àti èkejì rẹ̀.
9 Tí ó ń tẹ̀lé àsẹ mi,tí ó sì ń pa òfin mi mọ́ lotítọ́ àti lódodo.Ó jẹ́ olódodo,yóò yè nítòótọ́,ní Olúwa Ọlọ́run wí.
10 “Bí ó bá bi ọmọkùnrin, oniwà ipá, tó ń jalè, tó tún ń pànìyàn tó sì ń ṣe gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí sí arákùnrin rẹ̀
11 (bó tilẹ̀ jẹ́ pé baba rẹ kò se irú rẹ̀):“Ó ń jẹun lojúbọ lórí òkè gíga,o ba ìyàwó aládùúgbò rẹ̀ jẹ́.
12 Ó ni àwọn talákà àti aláìní lára,ó ń fipá jalè, kì í dá padà gẹ́gẹ́ bí ìlérí,o gbójú sókè sí òrìṣà,ó sì ń ṣe ohun ìríra.
13 Ó ń fowó ya ni pẹ̀lú èlé ó sì tún ń gba èlé tó pọ̀jù.Ǹjẹ́ irú ọkunrin yìí wa le è yè bí? Kò lè wá láàyè! Nítorí pé ó ti ṣe àwọn ohun ìríra yìí, yóò kú, ẹ̀jẹ̀ rẹ yóò sì wá lórí rẹ̀.