23 Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lú ọwọ ti mo gbé sókè, mo jẹ́jẹ̀ẹ́ fún wọn nínú ihà pé n ó tú wọn ka sì àárin àwọn orílẹ̀ èdè, ń ó sì fọ́n wọn káàkiri ilẹ̀ gbogbo,
24 nítorí pé wọn kò pa òfin mí mọ́, wọn sì tún kọ àsẹ mi sílẹ̀, wọn tún sọ ọjọ́ ìsinmi mi di aláìmọ́. Ọkàn wọn sì dúró ṣinṣin sọ́dọ̀ òrìṣà baba wọn.
25 Èmi náà sì fi wọn fún ìlànà tí kò dára àti òfin tí wọn kò le e yè nípa rẹ̀;
26 Mo jẹ́ kí ó sọ wọn di aláìmọ́ nípa ẹ̀bùn-nipa fífi àkọ́bí ọmọ wọn rú ẹbọ sísun àkọ́bí wọn la iná kọjá, kí ń lè kó ìpayà bá wọn, kí wọn le mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’
27 “Nítorí náà ọmọ ènìyàn, sọ fún ilé Ísírẹ́lì kí ó sì wí fún wọn pé, ‘Èyí ní ohun ti Olúwa Ọlọ́run wí: Nínú èyí náà, baba yín ti sọ̀rọ̀ àìtọ́ sí mi nípa kíkọ mi sílẹ̀.
28 Nígbà tí mo mú wọn dé ilẹ̀ tí mo ṣe ìlérí láti fún wọn, gbogbo igi ilẹ̀ gíga àti gbogbo igi to rúwé ni wọn tí ń rúbọ wọn ṣe irubọ to ń mú mi bínú, níbẹ̀ sì ni wọn ń ṣe òórùn dídùn wọn, ti wọn sì ń ta ọrẹ ohun mímu sílẹ̀.
29 Nígbà náà ni mo sọ fún wọn pé: Kí ní ibi gíga tí ẹ n lọ yìí?’ ” (Wọn sì ń pè ní Bámà di onì yìí.)