17 Èmi gan an yóò pàtẹ́wọ́ìbínú mi yóò sì rẹlẹ̀Èmi Olúwa ti sọ̀rọ̀.”
18 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ mi wá:
19 “Ọmọ ènìyàn la ọ̀nà méjì fín idà ọba Bábílónì láti gbà, kí méjèèjì bẹ̀rẹ̀ láti ìlú kan náà. Ṣe àmì sí ìkòríta ọ̀nà tí ó lọ sí ìlú náà.
20 La ọ̀nà kan fún idà láti wá kọ lu Rábà ti àwọn ará Ámónì kí òmíràn kọ lu Júdà, kí ó sì kọ lu Jérúsálẹ́mù ìlú olódi.
21 Nítorí ọba Bábílónì yóò dúró ni ìyànà ní ojú ọ̀nà, ní ìkóríta, láti wá àmìn nǹkan tí ń bọ̀: Yóò fi ọfà di ìbò, yóò bèèrè lọ́wọ́ àwọn òrìṣà rẹ̀, òun yóò ṣe àyẹ̀wò ẹ̀dọ̀.
22 Nínú ọwọ́ ọ̀tún rẹ ni ìbò Jérúsálẹ́mù yóò ti wá, ní ibi tí yóò ti gbé afárá kalẹ̀, láti pàṣẹ fún àwọn apànìyàn, láti mú ki wọn hó ìhó ogun láti gbé òòlù dí ẹnu ọ̀nà ibodè, láti mọ odi, àti láti kọ́ ilé ìṣọ́.
23 Yóò dàbí àmì èké sí àwọn tí ó ti búra ìtẹríba fún un, ṣùgbọ́n òun yóò ran wọn létí ẹbí wọn yóò sì mú wọn lọ sí ìgbèkùn.