8 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:
9 “Ọmọ ènìyàn, sọ tẹ́lẹ̀ wí pé, Èyí yìí ní Olúwa wí:“ ‘Ìdá kan, Ìdá kan,tí a pọ́n tí a sì kùn
10 a ti pọ́n fún pípa,a sì dan an kí ó lè máa kọ bí mọ̀nàmọ́ná!“ ‘Àwa yóò ha si ọ̀pá aládé ọmọ mi Júdà? Idà kẹ́gàn gbogbo ọ̀pá.
11 “ ‘Idà ní a yàn láti pọ́n,kí ó lè ṣe é gbá mú;a pọ́n ọn a sì dan án,ó ṣetán fún ọwọ́ àwọn apani.
12 Sunkún síta, kí ó sì pohùnréré ẹ̀kún, ọmọ ènìyàn,nítorí yóò wá sórí àwọn ènìyàn mi;yóò wá sórí gbogbo ọmọ aládé Ísírẹ́lììbẹ̀rù ńlá yóò wá sórí àwọn ènìyàn minítorí idà náà;nítorí náà lu oókan àyà rẹ.
13 “ ‘Ìdánwò yóò dé dandan. Tí ọ̀pá aládé Júdà èyí tí idà kẹ́gàn, kò bá tẹ ṣíwájú mọ́ ńkọ́? Ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.’
14 “Nítorí náà, ọmọ ènìyàn,sọ tẹ́lẹ̀ kí ó sì fí ọwọ́ lu ọwọ́Jẹ́ kí idà lu ara wọn lẹ́ẹ̀méjì,kódà ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta.Ó jẹ́ idà fún ìpànìyànidà fún ìpànìyàn lọ́pọ̀lọpọ̀Tí yóò sé wọn mọ́ níhìnín àti lọ́hùnnún.