17 Nígbà náà ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:
18 “Ọmọ ènìyàn, ilé Ísírẹ́lì ti di ìdárọ́ sí mi; gbogbo wọn jẹ́ bàbà, tánúnganran, ìrin àti òjé ti a fi sínú iná ìléru. Wọn jẹ́ ìdàrọ́ ti fàdákà.
19 Nítorí náà èyí yìí ni ohun ti Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Nítorí tí ìwọ ti di ìdárọ́, èmi yóò kó yín jọ sí Jérúsálẹ́mù.
20 Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ṣe ń kó fàdákà, bàbà, irin, òjé àti tánúnganran jọ sínú iná ìléru láti fi amúbí ina yọ́ ọ, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò kó ọ jọ ní ìbínú àti ìrunnú mi, èmi yóò sì fi ọ sì àárin ìlú, èmi yóò sì yọ́ ọ. Níbẹ̀ ní ìwọ yóò sì ti yọ́.
21 Èmi o ko yín jọ, èmi o sì fín iná ibínú mi si yin lára, ẹ o si di yíyọ́ láàrin rẹ̀.
22 Bí a ti ń yọ́ fàdákà nínú iná ìléru bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní ìwọ yóò se yọ́ nínú rẹ̀, ìwọ yóò sì mọ̀ wí pé èmi Olúwa ti tú ìbínú mi sórí rẹ.’ ”
23 Lẹ́ẹ̀kan síi ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé,