1 Ní ọdún kẹsàn án, oṣù kẹwàá, ọjọ́ kẹwàá, ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:
2 “Ọmọ ènìyàn, kọ ọjọ́ náà sílẹ̀, ọjọ́ náà gan an, nítorí Ọba Bábílónì náà ti dojúti Jérúsálẹ́mù ní ọjọ́ yìí gan an.
3 Sì pa òwe yìí fún ilé ọlọ́tẹ̀ náà, sọ fún wọn pé: ‘Èyí yìí ni Olúwa Ọlọ́run wí:“ ‘Gbé ìkòkò ìdáná náà ka iná:Gbé e kaná kí o sì da omi sí i nínú.
4 Kó àwọn ègé ẹran tí a gé náà sínú rẹ̀,gbogbo àwọn ègé ẹran tí ó tóbi, itan àti apá.Kó àwọn egungun tí ó dára jù sínú rẹ̀
5 Mú àwọn tí ó jọjú nínú agbo ẹran.Kó àwọn egungun sí abẹ́ ẹ rẹ̀;sì jẹ́ kí ó hó dára dárasì jẹ́ kí àwọn egungun náà bọ̀ nínú rẹ̀.