Ísíkẹ́lì 24:10-16 BMY

10 Nítorí náà kó igi náà jọ sí i,kí o sì fi iná sí i.Ṣe ẹran náà dáadáa,fi tùràrí dùn ún;ki o sì jẹ́ kí egungun náà jóná

11 Lẹ́yìn náà gbé òfìfo ìkòkò náà lórí ẹyin inákí idẹ rẹ̀ lè gbóná, kí ó lè pọ́nàti ki èérí rẹ̀ le di yíyọ́ nínú rẹ̀kí èrúrú rẹ̀ le jó dànù

12 Ó ti fi èké dá ara rẹ̀ lágara:èrúrú rẹ̀ kò sì jáde kúrò lára rẹ̀,èrúrú náà gan an yóò wà nínú iná.

13 “ ‘Nísìn yìí èérí rẹ̀ ni ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wà. Nítorí mo gbìyànjú láti wẹ̀ ọ́ mọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò sì mọ́ kúrò nínú ìwa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ, a kì yóò sì tún wẹ̀ ọ mọ́ kúrò nínú èèrí rẹ, títí èmi yóò fi jẹ́ kí ìbínú mi balẹ̀ sórí rẹ̀.

14 “ ‘Èmi Olúwa ni ó sọ ọ́, yóò sì ṣe, èmi yóò sì ṣe é. Èmi kì yóò pada sẹ́yìn; bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò dá sí i, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò yí ọkàn mi padà; gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ, àti gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ, ni wọn yóò dá ọ lẹ́jọ́, ni Olúwa Ọlọ́run wí.’ ”

15 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá pé:

16 “Ọmọ ènìyàn, kíyèsí i, mo mú ìfẹ́ ojú rẹ kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ, nípa lílù kan. Ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ gbààwẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ sunkún, bẹ́ẹ̀ ni omijé ojú rẹ kò gbọdọ̀ kán sílẹ̀.