17 Má ṣe sunkún, má ṣe gbààwẹ̀ fún òkú. Wé ọ̀já sí orí rẹ, sì bọ bàtà sí ẹsẹ̀ rẹ: má ṣe bo ètè ìsàlẹ̀ rẹ, ma ṣe jẹ oúnjẹ tí àwọn tí ń sọ̀fọ̀ ń jẹ gẹ́gẹ́ bí àṣà.”
18 Báyìí ni mo sọ̀rọ̀ fún àwọn ènìyàn ní òwúrọ̀, ní àṣálẹ́ ìyàwó mi sì kú. Ní òwúrọ́ ọjọ́ kejì, mo ṣe bí a ti pàsẹ fún mi.
19 Lẹ́yìn náà àwọn ènìyàn bi mí léèrè pé, “Ṣe o kò ni sọ fún wa ohun ti nǹkan wọ̀nyí ní láti ṣe pẹ̀lú wa?”
20 Mo sọ báyìí fún wọn pé, “Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:
21 Sọ fún ilé Ísírẹ́lì, ‘Báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí: Kíyèsí i, èmi yóò sọ ibi mímọ́ mi di ibi àìmọ́ títayọ agbára yín, ìfẹ́ ojú yín, ìkáànú yín, àti ọmọ yín ọkùnrin àti àwọn ọmọ yín obìnrin tí ẹ̀yin fi sílẹ̀ sẹ́yìn yóò ṣubú nípa idà.
22 Ẹyin yóò sì ṣe bí mo ti ṣe. Ẹ̀yin kì yóò bo ìsàlẹ̀ ojú yín tàbí jẹ oúnjẹ ti àwọn tí ń sọ̀fọ̀ ń jẹ gẹ́gẹ́ bí àṣà.
23 Ẹ̀yin yóò fi àwọn ọ̀já wé àwọn orí i yín àti àwọn bàtà ni ẹsẹ̀ yín, ẹ̀yin kì yóò sọ̀fọ̀ tàbí sunkún, ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò ṣòfò dànù nítorí àwọn àìṣedédé yín, ẹ̀yin yóò sì máa kérora láàrin ara yín.