4 Kó àwọn ègé ẹran tí a gé náà sínú rẹ̀,gbogbo àwọn ègé ẹran tí ó tóbi, itan àti apá.Kó àwọn egungun tí ó dára jù sínú rẹ̀
5 Mú àwọn tí ó jọjú nínú agbo ẹran.Kó àwọn egungun sí abẹ́ ẹ rẹ̀;sì jẹ́ kí ó hó dára dárasì jẹ́ kí àwọn egungun náà bọ̀ nínú rẹ̀.
6 “ ‘Nítorí báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí:“ ‘Ègbé ni fún ìlú ẹlẹ́jẹ̀ náà,fún ìkòkò náà tí èrúru wà nínú rẹ̀tí èrúru kò dà kúrò lójú rẹ̀!Mú ẹran náà jáde ní ekìrí ekìrímá ṣe ṣà wọ́n mú.
7 “ ‘Nítorí ẹ̀jẹ̀ tí ó ta sílẹ̀ wà ní àárin rẹ̀;o dà á sí orí àpáta kan lásánkò dà á sí orí ilẹ̀,níbi ti erùpẹ̀ yóò ti bò ó
8 Láti bá à le jẹ́ kí ìbínú kí ó dé láti gbẹ̀sanmo da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí orí àpáta kan lásán,kí o ma bà á wà ni bíbò.
9 “ ‘Nítorí náà báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí:“ ‘Ègbé ni fún ìlú ẹlẹ́jẹ̀ náà!Èmi pàápàá yóò jẹ́ kí òkítì iná náà tóbi.
10 Nítorí náà kó igi náà jọ sí i,kí o sì fi iná sí i.Ṣe ẹran náà dáadáa,fi tùràrí dùn ún;ki o sì jẹ́ kí egungun náà jóná