7 “ ‘Nítorí ẹ̀jẹ̀ tí ó ta sílẹ̀ wà ní àárin rẹ̀;o dà á sí orí àpáta kan lásánkò dà á sí orí ilẹ̀,níbi ti erùpẹ̀ yóò ti bò ó
8 Láti bá à le jẹ́ kí ìbínú kí ó dé láti gbẹ̀sanmo da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí orí àpáta kan lásán,kí o ma bà á wà ni bíbò.
9 “ ‘Nítorí náà báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí:“ ‘Ègbé ni fún ìlú ẹlẹ́jẹ̀ náà!Èmi pàápàá yóò jẹ́ kí òkítì iná náà tóbi.
10 Nítorí náà kó igi náà jọ sí i,kí o sì fi iná sí i.Ṣe ẹran náà dáadáa,fi tùràrí dùn ún;ki o sì jẹ́ kí egungun náà jóná
11 Lẹ́yìn náà gbé òfìfo ìkòkò náà lórí ẹyin inákí idẹ rẹ̀ lè gbóná, kí ó lè pọ́nàti ki èérí rẹ̀ le di yíyọ́ nínú rẹ̀kí èrúrú rẹ̀ le jó dànù
12 Ó ti fi èké dá ara rẹ̀ lágara:èrúrú rẹ̀ kò sì jáde kúrò lára rẹ̀,èrúrú náà gan an yóò wà nínú iná.
13 “ ‘Nísìn yìí èérí rẹ̀ ni ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wà. Nítorí mo gbìyànjú láti wẹ̀ ọ́ mọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò sì mọ́ kúrò nínú ìwa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ, a kì yóò sì tún wẹ̀ ọ mọ́ kúrò nínú èèrí rẹ, títí èmi yóò fi jẹ́ kí ìbínú mi balẹ̀ sórí rẹ̀.