9 “ ‘Nítorí náà báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí:“ ‘Ègbé ni fún ìlú ẹlẹ́jẹ̀ náà!Èmi pàápàá yóò jẹ́ kí òkítì iná náà tóbi.
10 Nítorí náà kó igi náà jọ sí i,kí o sì fi iná sí i.Ṣe ẹran náà dáadáa,fi tùràrí dùn ún;ki o sì jẹ́ kí egungun náà jóná
11 Lẹ́yìn náà gbé òfìfo ìkòkò náà lórí ẹyin inákí idẹ rẹ̀ lè gbóná, kí ó lè pọ́nàti ki èérí rẹ̀ le di yíyọ́ nínú rẹ̀kí èrúrú rẹ̀ le jó dànù
12 Ó ti fi èké dá ara rẹ̀ lágara:èrúrú rẹ̀ kò sì jáde kúrò lára rẹ̀,èrúrú náà gan an yóò wà nínú iná.
13 “ ‘Nísìn yìí èérí rẹ̀ ni ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wà. Nítorí mo gbìyànjú láti wẹ̀ ọ́ mọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò sì mọ́ kúrò nínú ìwa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ, a kì yóò sì tún wẹ̀ ọ mọ́ kúrò nínú èèrí rẹ, títí èmi yóò fi jẹ́ kí ìbínú mi balẹ̀ sórí rẹ̀.
14 “ ‘Èmi Olúwa ni ó sọ ọ́, yóò sì ṣe, èmi yóò sì ṣe é. Èmi kì yóò pada sẹ́yìn; bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò dá sí i, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò yí ọkàn mi padà; gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ, àti gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ, ni wọn yóò dá ọ lẹ́jọ́, ni Olúwa Ọlọ́run wí.’ ”
15 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá pé: