15 “Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí sí Tírè: Ǹjẹ́ àwọn erékùṣù kì yóò ha wárìrì nípa ìṣubú rẹ, nígbà tí ìkórìíra ìpalára àti rírẹ́ni lọ́run bá ń sẹlẹ̀ ní inú rẹ?
16 Nígbà náà ni gbogbo àwọn ọmọ aládé etíkun yóò sọ̀ kalẹ̀ láti orí ìtẹ́ wọn, wọn yóò sì pa àwọn aṣọ ìgúnwà wọn tì wọn yóò sì bọ́ àwọn ẹ̀wù wọn tí a ṣiṣẹ́ ọ̀nà sí lára kúrò. Ẹ̀rù yóò bò wọ́n, wọn yóò sì jòkòó lórí ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀, wọn yóò sì máa wárìrì ní gbogbo ìgbà, ẹnu yóò sì yà wọ́n sí ọ́.
17 Nígbà náà wọn yóò gbóhùn ẹkún sókè nítorí rẹ, wọn yóò sì wí fún ọ pé:“ ‘Báwo ni a se pa ọ́ run, ìwọ ìlú olókìkíìwọ tí àwọn èrò okun ti gbé inú rẹ̀!Ìwọ jẹ alágbára lórí okun gbogboòun àti àwọn olùgbé inú rẹ̀;ìwọ gbé ẹ̀rù rẹlórí gbogbo olùgbé ibẹ̀.
18 Nisin yìí erékùṣù wárìrìní ọjọ́ ìṣubú rẹ;erékùṣù tí ó wà nínú òkunni ẹ̀rù bà torí ìṣubú rẹ.’
19 “Èyí yìí ní Olúwa Ọlọ́run wí: Nígbà tí mo bá sọ ọ́ di ìlú ahoro, gẹ́gẹ́ bi àwọn ìlú tí a kò gbé inú wọn mọ́, àti nígbà tí èmi yóò mú ibú agbami òkun wá sí orí rẹ, omi ńlá yóò sì bò ọ́,
20 nígbà tí èmi yóò mú ọ wálẹ̀ pẹ̀lú àwọn tí ó sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú ihò, pẹ̀lú àwọn ènìyàn àtijọ́. Èmi yóò sì gbé ọ ibi ìsàlẹ̀, ní ibi ahoro àtijọ́, pẹ̀lú àwọn tí ó sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú ihò, ìwọ kì yóò sì padà gbé inú rẹ̀ mọ́, èmi yóò sì gbé ògo kalẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn alààyè.
21 Èmi yóò ṣe ọ ní ẹ̀rù, ìwọ kì yóò sì sí mọ́. Bí a tilẹ̀ wá ọ, ṣíbẹ̀ a kì yóò tún rí ọ mọ́, ní Olúwa Ọlọ́run wí.”