7 Asọ funfun dáradára tí a fi abẹ́rẹ́ṣiṣẹ́ ọ̀nà sí lára láti Éjíbítì wáni èyí tí ìwọ ta láti se okun ọkọ̀aṣọ aláró àti elésèé àlùkòláti erékùṣù ti Èlíṣàni èyí tí a fi bò ó
8 Àwọn ará ìlú Sídónì àti Árífádì ni àwọn ìtukọ̀ rẹ̀àwọn ọlọ́gbọ́n ẹ̀rọ rẹ, ìwọ Tírè,tí wọ́n wà nínú rẹ ni àwọn àtukọ̀ rẹ.
9 Àwọn àgbà Gíbálì,àti àwọn ọlọ́gbọ́n ibẹ̀,wà nínú ọkọ̀ bí òṣìṣẹ́ atukọ̀ rẹ,gbogbo ọkọ̀ ojú òkunàti àwọn atukọ̀-òkunwá pẹ̀lú rẹ láti dòwò pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.
10 “ ‘Àwọn ènìyàn Páṣíà, Lídíà àti Pútìwà nínú jagunjagun rẹàwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ.Wọ́n gbé àpáta àti àsíborí wọn rósára ògiri rẹ,wọn fi ẹwà rẹ hàn.
11 Àwọn ènìyàn Árífádì àti Hélékìwà lórí odi rẹ yíká;àti àwọn akọni Gámádì,wà nínú ilé ìṣọ́ rẹ.Wọ́n fi àwọn asà wọn kọ ara odi rẹ;wọn ti mú ẹwà rẹ pé.
12 “ ‘Táṣíṣì ṣòwò pẹ̀lú rẹ torí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ tí ó ní; wọn ṣe ìpààrọ̀ fàdákà, irin tanúnganran àti òjé fún ọjà títà rẹ̀.
13 “ ‘Àwọn ará Gíríkì, Túbálì, Jáfánì àti Méṣékì, ṣòwò pẹ̀lú rẹ: wọ́n fi ẹrù àti ohun èlò idẹ ṣe pàsípààrọ̀ fún ọrọ̀ rẹ.