1 Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé:
2 “Ọmọ ènìyàn, sọ fún ọmọ-aládé Tírè pé, ‘Báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí:“ ‘Nítorí tí ọkàn rẹ gbé sókè simiìwọ wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run;Èmi jókòó sí orí ìtẹ́ òrìṣàní àárin gbùngbùn òkun.”Ṣùgbọ́n ènìyàn ni ọ́, kì i ṣe òrìṣà,bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ rò pé ìwọ gbọ́n bí Ọlọ́run.
3 Ìwọ gbọ́n ju Dáníẹ́lì lọ bí?Ṣé kò sí àsírí kan tí ó pamọ́ fún ọ?
4 Pẹ̀lú ọgbọ́n àti ìmọ̀ rẹìwọ tí jèrè ọrọ̀ fún ara rẹàti àkójọpọ̀ wúrà àti fàdákànínú àwọn ilé ìṣúra rẹ.