18 Nípa ẹ̀ṣẹ̀ púpọ̀ rẹ àti òwò àìsòótọ́ rẹìwọ ti ba àwọn ibi mímọ́ rẹ jẹ́.Nítorí náà mo mú kí iná jáde wá látiinú rẹ, yóò sì jó ọ run,èmi yóò sì sọ ọ́ di eérú lórí ilẹ̀lójú gbogbo àwọn tí ó ń wò ọ́.
19 Gbogbo orílẹ̀ èdè tí ó mọ̀ ọ́ní ẹnu ń yà sí ọ;ìwọ yóò sì jẹ́ ẹ̀rùìwọ kì yóò sì sí mọ́ láéláé.’ ”
20 Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé:
21 “Ọmọ ènìyàn, kọ ojú sí Sídónì; kí o sì ṣọtẹ́lẹ̀ sí i
22 Kí ó sì wí pé: ‘Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí:“ ‘Èmi lòdì sí ọ, ìwọ Sídónì,a ó sì ṣe mí lógo láàárin rẹ.Wọn yóò, mọ̀ pé èmi ní Olúwa,Nígbà tí mo bá mú ìdájọ́ mi ṣẹ nínú rẹtí a sì yá mí sí mímọ́ nínú rẹ,
23 Èmi yóò sì rán àjàkálẹ̀-àrùn sínú rẹèmi yóò sì mú kí ẹ̀jẹ̀ ṣàn ní ìgboro rẹẹni ti á pa yóò ṣubú ní àárin rẹpẹ̀lú idà lára rẹ ní gbogbo ẹ̀gbẹ́nígbà náà wọn yóò mọ̀ wí pé èmi ni Olúwa.
24 “ ‘Kì yóò sì sí ẹ̀gún tí ń gun ni ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì mọ́, tàbí ẹ̀gún bíbani nínú jẹ́ ti gbogbo àwọn tí wọn wà ní àyíká wọn, tí wọ́n sì ń fi ojú yẹpẹrẹ wò wọ́n, nígbà náà ni wọn yóò mọ́ wí pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run.