4 Pẹ̀lú ọgbọ́n àti ìmọ̀ rẹìwọ tí jèrè ọrọ̀ fún ara rẹàti àkójọpọ̀ wúrà àti fàdákànínú àwọn ilé ìṣúra rẹ.
5 Nípa ọgbọ́n rẹ ńlá àti nípa òwò rẹìwọ ti sọ ọrọ̀ rẹ di púpọ̀àti nítorí ọrọ̀ rẹ di púpọ̀,ọkàn rẹ gbé sókèNitorí ọrọ̀ rẹ.
6 “ ‘Nítorí náà èyí yìí ní Olúwa Ọlọ́run wí:“ ‘Nítorí pé ìwọ rò pé o gbọ́n,pé ìwọ gbọ́n bí Ọlọ́run
7 Èmi yóò mú kí àwọn àjòjì dìde sí ọ,ẹlẹ́rù nínú àwọn orílẹ̀ èdè;wọn yóò yọ idà wọn sí ọẹwà rẹ àti ọgbọ́n rẹwọn yóò sì ba dídán rẹ̀ jẹ́.
8 Wọn yóò mú ọ sọ̀ kalẹ̀ wá sínú ihòìwọ yóò sì kú ikú gbígbónáàwọn tí a pa ní àárin òkun.
9 Ṣé ìwọ yóò wá wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run,”ní ojú àwọn tí ó pa ọ́?Ìwọ yóò jẹ́ ènìyàn, kì í ṣe Ọlọ́run,ní ọwọ́ àwọn ti yóò pa ọ́
10 Ìwọ yóò kú ikú aláìkọlàní ọwọ́ àwọn àjòjìÈmi ni ó ti sọ ọ́, ní Olúwa Ọlọ́run wí.’ ”