1 Síwájú sí i, ó sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, jẹ ohun tí ó wà níwájú rẹ, jẹ ìwé tí a ká yìí; kí o sì lọ fi bá ilé Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀.”
2 Mo sì ya ẹnu mi, ó sì mú mi jẹ ìwé kíká náà.
3 Ó tún sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, jẹ ìwe tí mo fún ọ yìí, fi bọ́ inú àti ikùn rẹ.” Nígbà náà ni mo jẹ ẹ́, dídùn rẹ̀ dàbí oyin ní ẹnu mi.
4 Ó sì tún sọ fún mi pé: “Ọmọ ènìyàn, lọ ni ìsinsinyìí bámi sọ ọ̀rọ̀ mi fún ìle Ísírẹ́lì.
5 A kò rán ọ sí àwọn tó ń sọ èdè àjèjì tàbí tí èdè wọn ṣòro láti gbọ́, ṣùgbọ́n orílẹ̀ èdè Ísírẹ́lì ni mo rán ọ sí