3 Ó tún sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, jẹ ìwe tí mo fún ọ yìí, fi bọ́ inú àti ikùn rẹ.” Nígbà náà ni mo jẹ ẹ́, dídùn rẹ̀ dàbí oyin ní ẹnu mi.
4 Ó sì tún sọ fún mi pé: “Ọmọ ènìyàn, lọ ni ìsinsinyìí bámi sọ ọ̀rọ̀ mi fún ìle Ísírẹ́lì.
5 A kò rán ọ sí àwọn tó ń sọ èdè àjèjì tàbí tí èdè wọn ṣòro láti gbọ́, ṣùgbọ́n orílẹ̀ èdè Ísírẹ́lì ni mo rán ọ sí
6 kì í ṣe sí ọ̀pọ̀ ènìyàn tó ń sọ àjèjì èdè tàbí tí èdè wọn ṣòro láti gbọ́, àwọn tí ọ̀rọ̀ wọn le fún ọ láti gbọ́ yé. Dájúdájú bí mo bá rán ọ sí wọn, wọn ì bá sì fetí sílẹ̀ sí ọ.
7 Ṣùgbọ́n ilé Ísírẹ́lì kò fẹ́ gbọ́ tìrẹ nítorí pé wọn kò fẹ́ láti gbọ́ tèmi, torí pé aláìgbọ́ràn àti ọlọ́kàn líle ni gbogbo ilé Ísírẹ́lì.
8 Ṣùgbọ́n bí i ti wọn lèmi náà yóò ṣe jẹ́ kí ojú àti ọkàn rẹ le.
9 Èmi yóò ṣe iwájú orí rẹ bí òkúta tó le jùlọ àni tó le ju òkúta ìbọn lọ. Má ṣe bẹ̀rù wọn tàbí jẹ́ kí wọn ó dáyà já ọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdílé ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n.”