14 Èmi yóò sì mú kí Pátírọ́sì di ahoroèmi yóò fi ina sí Sóánìèmi yóò sì fi ìyà jẹ Tébésì
15 Èmi yóò tú ìbínú mi jáde sórí Pélúsíómùìlú odi Éjíbítìèmi yóò sì ké àkójọpọ̀ Jépésì kúrò
16 Èmi yóò ti iná bọ ÉjíbítìPélúsíómù yóò japoró ní ìroraÈfúùfù yóò jà ní TébésìMémìfísì yóò wà ìpọ́njú ní ìgbà gbogbo
17 Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ní Hẹ́lópónísè àti Búbásítìyóò ti ipa idà subúwọn yóò sì kó àwọn ìlú wọn ní ìgbèkùn
18 Ojú ọjọ́ yóò ṣókùnkùn ní Tápárebìnígbà tí mo bá já àjàgà Éjíbítì kúrò;níbẹ̀ agbára iyì rẹ̀ yóò dópinwọn yóò fi ìkùukùu bò óàwọn abúlé rẹ ní wọn yóò lọ sí ìgbèkùn.
19 Nítorí náà Èmi yóò mú ki ìjìyà wá sórí Éjíbítì,wọn yóò sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.’ ”
20 Ní ọjọ́ keje osù kìn-ín-ní ọdún kọkànlá ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: