5 Kúṣì àti Pútì, Lídíà àti gbogbo Árábù, Líbíyà àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ ìlérí yóò ṣubú nípa idà papọ̀ pẹ̀lú Éjíbítì.
6 “ ‘Èyí yìí ní Olúwa wí:“ ‘Àwọn alejò Éjíbítì yóò ṣubúagbára ìgbéraga rẹ yóò kùnàláti Mígídólì títí dé Ásúwánìwọn yóò ti ipa idà ṣubú láàárin rẹ;ní Olúwa Ọlọ́run wí:
7 Wọn yóò sì wàlára àwọn ilẹ̀ tí ó di ahoro,ìlú rẹ yóò sì wàní ara àwọn ìlú tí ó di ahoro.
8 Lẹ́yìn náà wọn yóò mọ̀ pé èmi ní Olúwa,nígbà tí mo bá gbé iná kalẹ̀ ní Ijíbítìtí gbogbo àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ bá parun.
9 “ ‘Ní ọjọ́ náà oníṣẹ́ yóò ti ọ̀dọ̀ mi jáde nínú ọkọ̀ ojú omi láti dẹ́rùbà Kúsì kúrò nínú ìtẹ́lọ́rùn rẹ̀. Ìrora yóò wá sórí wọn gẹ́gẹ́ bí ti ọjọ́ ìparun Éjíbítì: Kíyèsí i, ó dé.
10 “ ‘Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí:“ ‘Èmi yóò mú òpin bá ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọnènìyàn Éjíbítì láti ọwọ́ Nébukadinésárì ọba Bábílónì.
11 Òun àti àwọn ológun rẹ̀ẹ́rù àwọn orílẹ̀-èdèní a o mú wá láti pa ilẹ náà run.Wọn yóò fa idà wọn yọ sí Éjíbítìilẹ̀ náà yóò sì kún fún àwọn tí a pa.