Ísíkẹ́lì 30:7-13 BMY

7 Wọn yóò sì wàlára àwọn ilẹ̀ tí ó di ahoro,ìlú rẹ yóò sì wàní ara àwọn ìlú tí ó di ahoro.

8 Lẹ́yìn náà wọn yóò mọ̀ pé èmi ní Olúwa,nígbà tí mo bá gbé iná kalẹ̀ ní Ijíbítìtí gbogbo àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ bá parun.

9 “ ‘Ní ọjọ́ náà oníṣẹ́ yóò ti ọ̀dọ̀ mi jáde nínú ọkọ̀ ojú omi láti dẹ́rùbà Kúsì kúrò nínú ìtẹ́lọ́rùn rẹ̀. Ìrora yóò wá sórí wọn gẹ́gẹ́ bí ti ọjọ́ ìparun Éjíbítì: Kíyèsí i, ó dé.

10 “ ‘Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí:“ ‘Èmi yóò mú òpin bá ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọnènìyàn Éjíbítì láti ọwọ́ Nébukadinésárì ọba Bábílónì.

11 Òun àti àwọn ológun rẹ̀ẹ́rù àwọn orílẹ̀-èdèní a o mú wá láti pa ilẹ náà run.Wọn yóò fa idà wọn yọ sí Éjíbítìilẹ̀ náà yóò sì kún fún àwọn tí a pa.

12 Èmi yóò mú kí àwọn odò Náílì gbẹÈmi yóò sì ta ilẹ náà fún àwọn ènìyàn búburú:láti ọwọ́ àwọn àjòjì ènìyànÈmi yóò jẹ́ kí ilẹ̀ náà àti gbogbo ohun tí ó wá nínú rẹ ṣòfò.Èmi Olúwa ni ó ti sọ ọ́.

13 “ ‘Báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí:“ ‘Èmi yóò pa àwọn òrìṣà runÈmi yóò sì mú kí òpin dé báère òrìṣà gbígbẹ́ ni Nófìkò ní sí ọmọ aládé mọ́ ní Éjíbítì,Èmi yóò mú kí ìbẹ̀rù gba gbogbo ilẹ̀ náà.