18 “Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún ìjọ Éjíbítì kí o sì ránsẹ́ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀ àti òun àti àwọn ọmọbìnrin orílẹ̀ èdè alágbára, pẹ̀lú àwọn tí o lọ sí ìsàlẹ̀, kòtò.
19 Sọ fún wọn, ‘Ǹjẹ ìwọ ní ojú rere jù àwọn tí o kù lọ? Lọ sí ìsàlẹ̀ kí a sì tẹ́ ọ sí àárin àwọn aláìkọlà náà.’
20 Wọn yóò ṣubú láàárin àwọn tí a fi idà pa. A fa idà yọ; jẹ́ kí a wọ́ Éjíbítì kúrò pẹ̀lú gbogbo ìjọ rẹ̀.
21 Láti inú isà òkú alágbára tí í ṣe aṣáájú yóò sọ nípa Éjíbítì àti àwọn àlejò rẹ̀, ‘Wọn ti wá sí ìsàlẹ̀, wọn sì sùn pẹ̀lú aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa.’
22 “Ásíríà wà níbẹ̀ pẹ̀lú gbogbo jagun jagun rẹ̀; àwọn isà òkú àwọn tí a ti pa sì yí i ká, gbogbo àwọn tí ó ti ipa idà ṣubú.
23 Isà òkú wọn wà ní ibi tí ó jìnlẹ̀ gan an nínú kòtò. Gbogbo àwọn tí ó ti tan ẹ̀rù ká ilẹ̀ alààyè ní a pa, tí ó ti ipa idà ṣubú.
24 “Élámù wà níbẹ̀, o yí isà òkú rẹ̀ ká pẹ̀lú gbogbo ijọ rẹ̀. Gbogbo wọn ni a pa, àwọn tí ó ti ipa idà ṣubú. Gbogbo àwọn tí ó ti tan ẹ̀rù ká ilẹ̀ alààyè lọ sí ìsàlẹ̀ láìkọlà sí abẹ́ ilẹ̀. Wọ́n gba ìtìjú wọn pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ìsàlẹ̀ kòtò.