1 “Ọmọ ènìyàn, sọ tẹ́lẹ̀ sí àwọn òkè gíga Ísírẹ́lì kí o sì wí pé, ‘Ẹ̀yin òkè gíga Ísírẹ́lì gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa.
2 Èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Àwọn ọ̀tá sọ nípa yín pé, “Áà! Àwọn ibi gíga ìgbàanì ti di ohun ìní wa.” ’
3 Nítorí náà, sọtẹ́lẹ̀ kí ó sì wí pé, ‘Èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Nítorí pé wọn sọ ọ di ahoro, tí wọn sì ń dọdẹ rẹ ní gbogbo ọ̀nà kí ìwọ kí ó lè di ìní fún àwọn orílẹ̀ èdè tí ó kù, àti ohun ti àwọn ènìyàn ń sọ ọ̀rọ̀ ìríra àti ìdibàjẹ́ sí,
4 nítorí náà, Ẹ̀yin òkè gíga Ísírẹ́lì gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun: Èyí yìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí fún àwọn òkè gíga àti àwọn òkè kékèké, fún àfonífojì ńlá àti àfonífojì kékèké, fún àwọn ibi ìsọdahoro ìparun àti fún àwọn ìlú tí a ti kọ̀ sílẹ̀ tí a ti kó tí àwọn orílẹ̀ èdè tí ó kù ní àyíká sì fi ṣe ẹlẹ́yà