3 Nítorí náà, sọtẹ́lẹ̀ kí ó sì wí pé, ‘Èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Nítorí pé wọn sọ ọ di ahoro, tí wọn sì ń dọdẹ rẹ ní gbogbo ọ̀nà kí ìwọ kí ó lè di ìní fún àwọn orílẹ̀ èdè tí ó kù, àti ohun ti àwọn ènìyàn ń sọ ọ̀rọ̀ ìríra àti ìdibàjẹ́ sí,
4 nítorí náà, Ẹ̀yin òkè gíga Ísírẹ́lì gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun: Èyí yìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí fún àwọn òkè gíga àti àwọn òkè kékèké, fún àfonífojì ńlá àti àfonífojì kékèké, fún àwọn ibi ìsọdahoro ìparun àti fún àwọn ìlú tí a ti kọ̀ sílẹ̀ tí a ti kó tí àwọn orílẹ̀ èdè tí ó kù ní àyíká sì fi ṣe ẹlẹ́yà
5 Èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Ní ìgbóná ọkàn ní mo sọ̀rọ̀ lòdì sí Édómù, nítorí pẹ̀lú ayọ̀ àti ìyodì ní ọkàn wọn ní wọ́n sọ ilé mi di ohun ìní wọn, kí wọn kí o lè kó pápá oko tútù rẹ̀.’
6 Nítorí náà, sọtẹ́lẹ̀ nípa ilẹ̀ Ísírẹ́lì náà kí o sì sọ sí àwọn òkè gíga náà àti àwọn òkè kékèké, sí àwọn àfonífojì ńlá àti sí àwọn àfonífojì kéékèèkéé: ‘Èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi sọ̀rọ̀ nínú ìrunú owú mi nítorí pé ìwọ ti jìyà ìfiṣẹ̀sín àwọn orílẹ̀ èdè.
7 Nítorí náà, Èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi ṣe ìbúra nípa nína ọwọ́ mi sókè pé; àwọn orílẹ̀ èdè àyíká rẹ náà yóò jìyà ìfiṣẹ̀sín.
8 “ ‘Ṣùgbọ́n ìwọ, òkè gíga Ísírẹ́lì, yóò mú ẹ̀ka àti èso fún àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì, nítorí wọn yóò wá sílé ní àìpẹ́ yìí.
9 Èmi ń ṣe àníyàn fún ọ, èmi yóò sì fi rere wọ̀ ọ́; àwa yóò tu ọ́, àwa yóò sì gbìn ọ́,