Ísíkẹ́lì 39:10-16 BMY

10 Wọn kò ní nílo láti kó igi jọ láti inú pápá, tàbí gé e láti inú igbó, nítorí pé wọ́n yóò lé òhun ìjà ogun bi epo ìdáná. Wọn yóò sì kógun àwọn tí ó ṣe ìgárá sí wọn, wọn yóò sì bo ilé àwọn tí ó bo ilé wọn, ni Olúwa Ọba tẹnumọ́.

11 “ ‘Ní ọjọ́ náà èmi yóò sì fi ibi ìsìnkú fún Gógì ní Ísírẹ́lì, ni àfonífojì àwọn ti ó rìn ìrìnàjò lọ sí agbègbè ilà òòrùn òkun. Yóò di ojú ọ̀nà àwọn arìnrìn àjò, nítorí Gógì àti gbogbo ìjọ rẹ̀ ni àwa yóò sin síbẹ̀. Nítorí náà, a óò pè é ní àfonífojì tí Ámónì Gógì.

12 “ ‘Fún oṣù méje ní ilé Ísírẹ́lì yóò fi máa sìn wọ́n láti ṣe àfọ̀mọ́ ilẹ̀ náà.

13 Gbogbo ènìyàn ilẹ náà yóò sìn wọ́n, ọjọ́ tí a yìn mi lógo yóò jẹ́ ọjọ́ ìrántí, ní Olúwa Ọba wí.

14 “ ‘Wọn yóò gbà àwọn ènìyàn ṣíṣẹ́ lóòrèkóórè láti ṣe àfọ̀mọ́ náà. Ọ̀pọ̀ yóò lọ káàkiri ilẹ̀ náà, ní àfikún pẹ̀lú wọn, àwọn tó kù yóò sìn àwọn tí ó kú lórí ilẹ̀: Ní ìparí oṣù kéje wọn yóò bẹ̀rẹ̀ wíwá kiri wọn.

15 Bí wọ́n n lọ káàkiri ilẹ̀ náà ọ̀kan nínú wọn rí egungun ènìyàn, oun yóò gbé àmì ńlá kalẹ̀ ni ẹ̀gbẹ́ rẹ títí àwọn asìnkú yóò fi sìn ín ní àfonífojì Ámónì Gógì.

16 (Bákan náà ìlú kan tí a ń pè ni Ámónì yóò wà níbẹ̀). Nítorí náà wọn yóò wẹ ilẹ̀ náà:’