13 Lẹ́yìn náà, ó wọn ẹnu ọ̀nà láti òkè ẹ̀yìn ògiri yàrá kéékèèkéé kan títí dé òkè àdojúkọ ọ̀kan; jínjìn sí ara wọn jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ́dọ́gbọ̀n láti odi kan tí ó sí sílẹ̀ sí àdojúkọ ọ̀kan.
14 Ó wọ̀n ọ́n lọ sí àwọn ojú àwọn ìgbéró ògiri gbogbo rẹ̀ yí inú òjú ọ̀nà ó jẹ́ ọgọ́ta ìgbọ̀nwọ́. Ìwọ̀n náà tó àtẹ̀wọ́ ẹnu ọ̀nà tí ó dojúkọ àgbàlá.
15 Ìjìnà ẹnu ọ̀nà àbáwọlé títí dé ìparí yàrá kéékèèkéé náà àti àwọn ìgbéró ògiri nínú ẹnu ọ̀nà ní a gbé dá jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́.
16 Ni a tẹ nínú yíká; àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà ní fèrèsé tóóró tí ó wọ inú yíká; Awọn ògiri wọn ní inú ni a fi pákó tẹ yíká láti ilẹ̀ dé òkè fèrèsé ati láti fèrèsé dé òrùlé.
17 Lẹ́yìn náà ó mú mi lọ sí ojú òde àgbàlá. Níbẹ̀ mo rí yàrá díẹ̀ àti pèpéle tí a kọ́ yí àgbàlá ká; ọgbọ̀n yàrá wà lẹ́gbẹ̀ pèpéle náà,
18 O ṣe ààlà sí ẹ̀gbẹ́ àwọn ẹnu ọ̀nà, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ bákan náà pẹ̀lú gígun rẹ̀: èyí jẹ́ pèpéle tí ìsàlẹ̀.
19 Lẹ́yìn náà, o wọn jíjìnna rẹ̀ láti inú ìsàlẹ̀ ẹnu ọ̀nà títí dé àgbàlá tí inú; ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ni ìhà ìlà òòrùn àti tí àríwá.