48 Ó mú mi lọ sí àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà tẹ́ḿpìlì, ó sì wọn àwọn àtẹrígbà àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà; wọ́n jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn ún ní fífẹ̀, ẹ̀gbẹ́ méjèèjì rẹ̀. Fífẹ̀ àbáwọlé jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rìnlá, ìgbéró àwọn ògiri náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta ní fífẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì.