8 Lẹ́yìn náà, ó wọn àtẹ̀wọ́ ẹnu ọ̀nà:
9 Ó jẹ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́jọ ní jíjìn àtẹ́rígbà rẹ̀ sì jẹ ìgbọ̀nwọ́ méjì ní nínípọ̀n. Àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà kọjú sí tẹ́ḿpìlì.
10 Ní ẹnu ọ̀nà ìlà òòrùn ni àwọn yàrá kéékèèkéé mẹ́ta wà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan: mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kọ̀ jú sí ara wọn, ojú ìgbéró ògiri ni ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan jẹ́ bákan náà ní wíwọ̀n.
11 Lẹ́yìn náà ó wọn ìbú à bá wọ ẹnu ọ̀nà náà; ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wà, gígùn rẹ̀ sì jẹ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́tàlá.
12 Ní iwájú ọ̀kọ̀ọ̀kan yàrá kéékèèkéé kọ̀ọ̀kan ní ògiri tí gíga rẹ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan wà, ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àwọn yàrá kéékèèkéé sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà.
13 Lẹ́yìn náà, ó wọn ẹnu ọ̀nà láti òkè ẹ̀yìn ògiri yàrá kéékèèkéé kan títí dé òkè àdojúkọ ọ̀kan; jínjìn sí ara wọn jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ́dọ́gbọ̀n láti odi kan tí ó sí sílẹ̀ sí àdojúkọ ọ̀kan.
14 Ó wọ̀n ọ́n lọ sí àwọn ojú àwọn ìgbéró ògiri gbogbo rẹ̀ yí inú òjú ọ̀nà ó jẹ́ ọgọ́ta ìgbọ̀nwọ́. Ìwọ̀n náà tó àtẹ̀wọ́ ẹnu ọ̀nà tí ó dojúkọ àgbàlá.