15 Nígbà tí o parí nǹkan tí ó wà nínú ilé Ọlọ́run tán, o mú mi jáde lọ sí ọ̀nà tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn, ó sì wọn agbégbé náà yípo:
16 Ó wọn ìhà ìlà oòrùn pẹ̀lú ọ̀pá ìwọ̀n ǹnkan; ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́.
17 Ó wọn ìhà àríwá; ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ pẹ̀lú ọ̀pá ìwọn nǹkan.
18 O wọn ìhà gúsù; ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ pẹ̀lú ọ̀pá wíwọ̀n nǹkan.
19 Lẹ́yìn èyí ni ó wà yí padà sí ìhà ìwọ̀ oòrùn o sì wọ̀n ọ́n: ó sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ pẹ̀lú ọ̀pa wíwọ̀n.
20 Báyìí ní ó wọn agbégbé ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. Ó ní ògiri kan yípo rẹ̀, ọgọ́rùn-ún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ̀, àti ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, láti ya ibi mímọ́ sọ́tọ̀ kúrò ní ibi tí gbogbo ènìyàn ń lọ sọ́tọ̀.