1 Lẹ́yìn náà ọkùnrin náà mú mi gba ti ẹnu ọ̀nà tí ó dojúkọ ìhà ìlà oòrùn,
2 mo sì ri ògo Ọlọ́run Ísírẹ́lì ń bọ láti ìhà ìlà oòrùn. Ohùn rẹ̀ dàbí híhó omi, ìtànsán ògo rẹ̀ sì bo ilẹ̀.
3 Ìran tí mo rí dàbí ìran tí mo rí lẹ́bàá odò Kébárì, mo sì dorí kodò.
4 Ògo Olúwa gba ọ̀nà tí o dojúkọ ìhà ìlà oòrùn wọ inú ilé Ọlọ́run wá.