Ísíkẹ́lì 43:11-17 BMY

11 tí ojú gbogbo ohun tí wọn ti ṣe bá tì wọ́n, jẹ́ kí wọ́n mọ̀ àwòrán ilé Ọlọ́run náà bí wọ́n ṣe tò ó lẹ́sẹẹsẹ, àbájáde àti àbáwọlé rẹ̀ gbogbo àwòrán àti gbogbo òfin àti ìlànà rẹ̀. Kọ ìwọ̀nyí sílẹ̀ ní iwájú wọn kí wọn kí ó lè jẹ́ olóòtọ́ si àwòrán rẹ̀, kí wọ́n sì tẹ̀lé gbogbo òfin rẹ̀.

12 “Èyí yìí ní òfin ilé Ọlọ́run náà: Gbogbo àyíká lórí òkè gíga ní yóò jẹ́ ibi mímọ́ jùlọ. Bí èyí ni òfin tẹ́ḿpìlì náà.

13 “Ìwọ̀nyí ni wíwọ̀n pẹpẹ ìrúbọ ní gígùn ìgbọ̀nwọ́, ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ni jíjìn, ó sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ni fífẹ̀, igun rẹ̀ yípo àti etí rẹ̀ jẹ́ ibú àtẹ́lẹwọ́ kan: Èyí yìí sì ni gíga pẹpẹ ìrúbọ náà:

14 Láti ìsàlẹ̀ rẹ̀ ni ilẹ̀ títí dé ìsàlẹ̀ igun rẹ̀, ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì ni gíga o sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ní fífẹ̀:

15 Ibi ìdáná pẹpẹ ìrúbọ náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní gíga, ìwo mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sì yọrí jáde sókè láti ibi ìdáná.

16 Ibi ìdáná pẹpẹ náà jẹ́ igun mẹ́rin mẹ́rin lọ́gbọgba, ìgbọ̀nwọ́ méjìlá ní gígùn, o sì jẹ ìgbọ̀nwọ́ méjìlá ní fífẹ̀.

17 Igun ni apá òkè náà jẹ́ igun mẹ́rin lọ́gbọgba, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rìnlá ní gígùn, ó sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rìnlá ní fífẹ̀, pẹ̀lú etí tí ó jẹ́ ìdáji ìgbọ̀nwọ́, ìsàlẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan yípo. Àtẹ̀gùn pẹpẹ ìrúbọ náà dojúkọ ìlà oòrùn.”