Ísíkẹ́lì 45:11-17 BMY

11 Éfà àti batì gbọdọ̀ jẹ́ bákan náà, kí bátì tí ó gba ìdàmẹ́wàá hómérì, àti ẹfa ìdámẹ́wàá hómérì: Hómérì ni kí ó jẹ́ òṣùnwọ̀n tí wọn yóò lò fún méjèèjì.

12 Ṣékélì ní kí o gba ogún gérà. Ogún ṣekeli pẹ̀lú ṣékélì márùndínlọ́gbọ̀n pẹ̀lú ṣékélì mẹ́ẹ̀dógún yóò jẹ́ mínà kan.

13 “ ‘Èyí yìí ni ẹ̀bùn pàtàkì tí o gbọdọ̀ ṣe: éfà kẹ́fà láti inú hómérì ọkà kọ̀ọ̀kan àti éfà kẹ́fà láti inú hómérì báálì kọ̀ọ̀kan.

14 Ìpín òróró tí a júwe, tí a fi bátì wọ̀n, ni ìdámẹ̀wàá bátì láti inú kórì (èyí tí ó gba ìdámẹ́wàá bati tàbí hómérì kan, fún ìdámẹ̀wàá bátì jẹ́ bákan náà sì hómérì kan.)

15 Bákan náà ni àwa yóò mú àgùntàn kan láti inú agbo ẹran tí ó jẹ́ igba láti inú kanga omi pápá oko tútù tí Ísírẹ́lì. Ìwọ̀nyí ni wọn yóò lò fún àwọn ọrẹ ẹbọ jíjẹ, ẹbọ sísun àti ìdàpọ̀ ọrẹ ẹbọ láti ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún àwọn ènìyàn, ní Olúwa Ọba sọ.

16 Gbogbo ènìyàn ni ilẹ̀ náà ni yóò kópa nínú ẹ̀bùn pàtàkì fún ìlò àwọn ọmọ aládé ni Ísírẹ́lì.

17 Yóò jẹ́ ojúṣe ọmọ aládé láti pèsè ọrẹ ẹbọ sísun, ọrẹ ẹbọ jíjẹ àti ọrẹ ẹbọ mímu níbi àṣè gbogbo, ti oṣù tuntun àti ní àwọn ọjọ ìsìnmi ni gbogbo àjọ ilé Ísírẹ́lì. Oun yóò pèsè ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ọrẹ ẹbọ jíjẹ, ọrẹ ẹbọ sísun àti ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀, láti ṣe ètùtù fún ilé Ísírẹ́lì.