4 Yóò jẹ́ ibi mímọ́ lára ilẹ̀ náà fún àwọn àlùfáà, tí ó ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ ní ibi mímọ́ àti àwọn tí ó súnmọ́ àlùfáà ní iwájú Olúwa. Ibẹ̀ yóò jẹ ibi tí yóò wà fún ilé gbígbé wọn, bákan náà ni yóò jẹ́ ibi mímọ́ fún ilé Olúwa.
5 Agbègbè kan tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní fífẹ̀ yóò jẹ́ ti àwọn ará Léfì, tí ó ń ṣiṣẹ ìránṣẹ́ nínú tẹ́ḿpìlì, gẹ́gẹ́ bi ìní wọn fún ìlú wọn láti máa gbé ibẹ̀.
6 “ ‘Ìwọ yóò fi ìlú náà ti agbègbè rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ni fífẹ̀ àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, papọ̀ mọ́ ibi mímọ́ fún àwọn ilé Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ìní: yóò jẹ́ ti gbogbo ilé Ísírẹ́lì.
7 “ ‘Àwọn ọmọ aládé ni yóò bá ibi mímọ́ pààlà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan agbégbé tí ó jẹ ibi mímọ́ àti ohun tí ó jẹ́ ti ìlú. Yóò fẹ̀ sẹ́yìn sí ìhà ìwọ̀ oòrùn láti apá ìwọ̀ oòrùn àti si ìlà oòrùn, láti apá ìlà oòrùn, gígùn rẹ̀ yóò jẹ́ láti ìwọ̀ oòrùn sí ààlà ìlà oòrùn, ti ìṣe déédéé rẹ̀ yóò jẹ́ ti ọ̀kan lára àwọn ìpín ẹ̀yà.
8 Ilẹ̀ yìí ni yóò jẹ́ ìpín rẹ̀ ní Ísírẹ́lì. Àwọn ọmọ aládé mìíràn kò ní rẹ́ àwọn ènìyàn mi jẹ mọ́, ṣùgbọ́n wọn yóò jẹ́ kí àwọn ilé Ísírẹ́lì gba ilẹ̀ wọn gẹ́gẹ́ bi ẹ̀yà wọn.
9 “ ‘Èyí yìí ni Olúwa Ọba wí: Ìwọ ti rìn jìnnà tó, Ẹ̀yin ọmọ aládé tí Ísírẹ́lì! Fi ìwà ipá àti ìrẹ́jẹ rẹ sílẹ̀ kí ó sì se èyí tí ó tọ́ àti èyí tí ó yẹ. Dáwọ́ gbígbà lọ́wọ́ àwọn ènìyàn mi dúró, ni Olúwa Ọba sọ.
10 Ìwọ gbọdọ̀ lo òṣùnwọ̀n tó tọ́ àti efà títọ́ àti bátì títọ́.