8 Ilẹ̀ yìí ni yóò jẹ́ ìpín rẹ̀ ní Ísírẹ́lì. Àwọn ọmọ aládé mìíràn kò ní rẹ́ àwọn ènìyàn mi jẹ mọ́, ṣùgbọ́n wọn yóò jẹ́ kí àwọn ilé Ísírẹ́lì gba ilẹ̀ wọn gẹ́gẹ́ bi ẹ̀yà wọn.
9 “ ‘Èyí yìí ni Olúwa Ọba wí: Ìwọ ti rìn jìnnà tó, Ẹ̀yin ọmọ aládé tí Ísírẹ́lì! Fi ìwà ipá àti ìrẹ́jẹ rẹ sílẹ̀ kí ó sì se èyí tí ó tọ́ àti èyí tí ó yẹ. Dáwọ́ gbígbà lọ́wọ́ àwọn ènìyàn mi dúró, ni Olúwa Ọba sọ.
10 Ìwọ gbọdọ̀ lo òṣùnwọ̀n tó tọ́ àti efà títọ́ àti bátì títọ́.
11 Éfà àti batì gbọdọ̀ jẹ́ bákan náà, kí bátì tí ó gba ìdàmẹ́wàá hómérì, àti ẹfa ìdámẹ́wàá hómérì: Hómérì ni kí ó jẹ́ òṣùnwọ̀n tí wọn yóò lò fún méjèèjì.
12 Ṣékélì ní kí o gba ogún gérà. Ogún ṣekeli pẹ̀lú ṣékélì márùndínlọ́gbọ̀n pẹ̀lú ṣékélì mẹ́ẹ̀dógún yóò jẹ́ mínà kan.
13 “ ‘Èyí yìí ni ẹ̀bùn pàtàkì tí o gbọdọ̀ ṣe: éfà kẹ́fà láti inú hómérì ọkà kọ̀ọ̀kan àti éfà kẹ́fà láti inú hómérì báálì kọ̀ọ̀kan.
14 Ìpín òróró tí a júwe, tí a fi bátì wọ̀n, ni ìdámẹ̀wàá bátì láti inú kórì (èyí tí ó gba ìdámẹ́wàá bati tàbí hómérì kan, fún ìdámẹ̀wàá bátì jẹ́ bákan náà sì hómérì kan.)