Ísíkẹ́lì 46:9-15 BMY

9 “ ‘Nígbà tí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà bá wá ṣíwájú Olúwa ni àwọn àjọ tí a yàn, ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ti ẹnu ọ̀nà ìhà àríwá wọlé láti jọ́sìn gbọdọ̀ gba ti ẹnu ọ̀nà ìhà gúsù jáde; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gba tí ẹnu ọ̀nà ìhà àríwá jáde. Kò sí ẹni tí ó gbọdọ̀ gba ibi tí ó bá wọlé padà, ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù gba òdìkejì ẹnu ọ̀nà tí ó gbà wọlé jáde.

10 Ọmọ aládé gbọdọ̀ wà ní àárin wọn, kí ó wọlé nígbà tí wọn bá wọlé, kí ó sì jáde nígbà tí wọn bá jáde.

11 “ ‘Níbi àwọn àjọ̀dún àti àwọn àjọ tí a yàn, ọrẹ ẹbọ jíjẹ gbọdọ̀ jẹ́ éfà kan pẹ̀lú àgbò kan, àti pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn gẹ́gẹ́ bí ó bá se wu onílúlùkù, Pẹ̀lú hini òróró kan fún éfà kan.

12 Nígbà tí ọmọ aládé bá pèsè ọrẹ àtinúwá fún Olúwa yálà ọrẹ ẹbọ sísun tàbí ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀ ojú ọ̀nà tí ó dojúkọ ìhà ìlà oòrùn ni kí ó wà ni sísí sílẹ̀ fún-un Òun yóò rú ọrẹ ẹbọ sísun rẹ̀ tàbí ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀ gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe ní ọjọ́ ìsinmi. Lẹ́yìn náà, oun yóò jáde, lẹ́yìn ìgbà tí ó bá jáde tán wọn yóò ti ẹnu ọ̀nà.

13 “ ‘Ní ojoojúmọ́ ni ìwọ yóò pèsè ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan aláìlábùkù fún ọrẹ ẹbọ sísun sí Olúwa; àràárọ̀ ni ìwọ yóò máa pèsè rẹ̀.

14 Ìwọ yóò sì máa pèsè ọrẹ ẹbọ jíjẹ pẹ̀lú rẹ̀ ní àràárọ̀, èyí yóò ni ìdámẹ́fà nínú éfà àti ìdámẹ́fà nínú òróró hínì láti fi po ìyẹ̀fun. Gbígbé ọrẹ ẹbọ jíjẹ fún Olúwa jẹ́ ìlànà tí ó wà títí.

15 Nítorí náà ọ̀dọ́ àgùntàn àti ọrẹ ẹbọ jíjẹ àti òróró ni wọn yóò pèsè ní àràárọ̀ fún ọrẹ ẹbọ sísun ìgbà gbogbo.