1 “Báyìí, ọmọ ènìyàn, mú ìdá tí ó mú kí o sì fi se abẹ ìfárí onígbàjámọ̀, kí o fi fá irun orí àti irùngbọ̀n rẹ. Fi irun yìí sórí ìwọ̀n kí o sì pín in.
2 Nígbà tí ọjọ́ ìgbóguntì bá parí, sun ìdá kan nínú ìdá mẹ́ta ìrun yìí níná láàrin ìlú. Mú ìdá kan nínú mẹ́ta kí o fi idà bù ú káàkiri ìlú. Kí o sì tú ìdá kan yóòkù ká sínú afẹ́fẹ́. Nítorí pé pẹ̀lú idà ni èmi yóò máa lé wọn ká.
3 Ṣùgbọ́n mú díẹ̀ nínú irun yìí kí o sì ta á mọ́ etí aṣọ rẹ.
4 Tún ju díẹ̀ nínú irun yìí sínú iná, kí o sun ún níná. Torí pé láti ibẹ̀ ni iná yóò ti jáde lọ sí gbogbo ilé Ísírẹ́lì.