14 “Èmi yóò fi ọ́ ṣòfò, ó sì sọ ọ́ di ẹ̀gàn fún àwọn orílẹ̀ èdè tó yí ọ ká, àti lójú àwọn tó ń kọjá
15 O ó wá di ẹ̀gàn, ẹ̀sín àti ikílọ àti ohun ẹ̀rù àti ìyanu fún àwọn orílẹ̀ èdè tó yí ọ ká nígbà tí mo bá fìyà jẹ ọ́ nínú ìbínú àti nínú ìbínú gbígbóná mi. Èmi Olúwa ni ó sọ bẹ́ẹ̀.
16 Nígbà tí mo bá ta ọfà ikú àti ìparun pẹ̀lú ìyàn, n ó ta á láti run ọ́ ni. N ó gé ìpèsè oúnjẹ kúrò, n ó sì mú ìyàn wá lọ́pọ̀lọpọ̀.
17 Èmi yóò rán ìyàn àti ẹranko búburú sí i yín, wọn yóò fi yín sílẹ ni àìlọ́mọ. Àjàkálẹ̀ àrùn àti ìtàjẹ̀-sílẹ̀ yóò kọjá láàrin yín. Èmi yóò si mú idà wá sórí rẹ. Èmi Olúwa ló sọ bẹ́ẹ̀.”