Ísíkẹ́lì 5:5-11 BMY

5 “Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Èyí ní Jérúsálẹ́mù, tí mo gbé kalẹ̀ sí àárin àwọn orílẹ̀ èdè, pẹ̀lú àwọn ìlú gbogbo tí o yí i ká.

6 Síbẹ̀ nínú ìwà búburú rẹ̀ ó ti ṣọ̀tẹ̀ si òfin àti ìlànà mi ju àwọn orílẹ̀ èdè àti àwọn ilẹ̀ tó yí i ká lọ. Ó ti kọ òfin mi sílẹ̀, kò sì pa ìlànà mi mọ́.

7 “Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Nítorí pé o ti ṣe àìgbọ́ràn ju àwọn orílẹ̀ èdè tó yí ọ ká lọ, tí o kò sì tẹ̀lé ìlànà mi tàbí kí o pa òfin mi mọ́. O kò tilẹ̀ tún ṣe dáadáa tó àwọn orílẹ̀ èdè tó yí ọ ká.

8 “Nítorí náà báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Èmi gan an lòdì sí ọ, Jérúsálẹ́mù, n ó sì jẹ ọ́ níyà lójú àwọn orílẹ̀ èdè tó yí ọ ká.

9 Nítorí ìwà ìbọ̀rìṣà rẹ, n ó ṣe ohun tí n kò tí ì ṣe rí láàrin rẹ àti èyí tí n kò ní í ṣe irú rẹ̀ mọ́.

10 Nítorí náà láàrin rẹ àwọn baba yóò má a jẹ ọmọ wọn, àwọn ọmọ náà yóò máa jẹ baba wọn. N ó jẹ ọ́ níyà, n ó sì tú àwọn tó bá ṣẹ́kù ká sínú èfúùfù.

11 Nítorí náà, Olúwa Ọlọ́run wí pé, bí mo ṣe wà láàyè, nítorí pé o ti sọ ibi mímọ́ mi di àìmọ́ pẹ̀lú àwọn àwòrán ẹ̀gbin àti àwọn ohun ìríra rẹ, n ó mú ojú rere mi kúrò lára rẹ n kò ní í da ọ sí tàbí wò ọ́ pẹ̀lú àánú mọ́.