1 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá wí pé:
2 “Ọmọ ènìyàn, dojú kọ àwọn òkè Ísírẹ́lì; kí o sì sọtẹ́lẹ̀ lòdì sí wọn
3 wí pé: ‘Ẹ̀yin òkè Ísírẹ́lì, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run. Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí sí ẹ̀yin òkè ńlá àti àwọn òkè kékèké sí àwọn odò ṣíṣàn àti sí àfonífojì, n ó mú idà wa sórí yín, n ó sì pa ibi gíga yín run.
4 N ó wó pẹpẹ yín lulẹ̀, n ó sì fọ́ pẹpẹ tùràrí yín túútúú; èmi ó sì pa àwọn ènìyàn yín síwájú àwọn òrìṣà wọn.
5 N ó tẹ́ òkú àwọn ará Ísírẹ́lì síwájú òrìsà wọn n ó sì fọ́n egungun wọn yí pẹpẹ wọn ká.
6 Gbogbo ibi tí ẹ ń gbé àti àwọn ibi gíga yín ni yóò di píparun, gbogbo pẹpẹ yín ni yóò di ahoro, àwọn òrìṣà yín yóò di fífọ́ túútúú, àwọn pẹpẹ tùràrí yín ni a ó gé lulẹ̀, gbogbo iṣẹ́ yín yóò parẹ́.