11 “ ‘Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí: Pàtẹ́wọ́ kí o tún fẹsẹ̀ janlẹ̀, kí o wá kígbe síta pé, “Ó ṣe!” ilé Ísírẹ́lì yóò ṣubú nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn nítorí gbogbo ìwà ìríra búburú tí wọ́n hù. Wọn yóò ṣubú nípa idà àti ìyàn.
12 Ẹni tó wà lókèèrè yóò kú pẹ̀lú àjàkálẹ̀-àrùn, àti ẹni tó wà nítòsí yóò ṣubú pẹ̀lú idà, ìyàn ni yóò pa ẹni tó bá ṣẹ́kù sílẹ̀. Báyìí ni n ó ṣe mú ìbínú gbígbóná mi wá sórí wọn.
13 Wọn yóò sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa, nígbà tí òkú àwọn ènìyàn wọn bá wà níbẹ̀ láàrin òrìṣà wọn yí pẹpẹ wọn ká, lórí àwọn òkè gíga gbogbo, àti lórí góńgó òkè àti lábẹ́ igi tútù àti lábẹ́ igi óákù-níbi tí wọ́n ti ń fi tùràrí dídùn rúbọ̀ sí gbogbo òrìṣà wọn.
14 Èmi yóò na ọwọ́ mi jáde sí wọn láti mú kí ilẹ̀ náà ṣòfò kí ó sì dahoro dé aṣálẹ̀ ìhà Díbílà-ní gbogbo ibùgbé wọn. Nígbà náà ni wọn ó mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.’ ”