21 Èmi yóò sì fi àwọn ǹnkan wọ̀nyí ṣe ìjẹ fún àlejò àti fún àwọn ènìyàn búburú ayé, wọn ó sì sọ ọ di aláìmọ́.
22 Èmi yóò gbójú mi kúrò lára wọn, wọn ó sì sọ ibi iṣúra mi di aláìmọ́; àwọn ọlọ́ṣà yóò wọ inú rẹ̀ wọn ó sì bà á jẹ́
23 “Rọ ẹ̀wọ̀n irin, torí pé ilẹ̀ náà kún fún ẹ̀ṣẹ̀ ìtàjẹ̀sílẹ̀, ìlú náà sí kún fún ìwà ipá.
24 Èmi yóò mú kí orílẹ̀ èdè ti búburú rẹ pọ̀ jù gba ilé wọn; ń ó sì fi òpin sí ìgbéraga àwọn alágbára, ibi mímọ́ wọn yóò sì di bíbàjẹ́.
25 Nígbà tí ìpayà bá dé, wọn ó wá àlàáfíà, ṣùgbọ́n kò ní sí
26 Wàhálà lórí wàhálà yóò dé, ìdágìrì sókè lórí ìdágìrì, Nígbà náà ni wọn ó wá ìran lọ́dọ̀ wòlíì; ṣùgbọ́n ẹ̀kọ́ òfin yóò parun lọ́dọ̀ àlùfáà, bẹ́ẹ̀ ni ìmọ̀ràn yóò ṣègbé lọ́dọ̀ àwọn alàgbà.
27 Ọba yóò sọ̀fọ̀, ọmọ aláde yóò wà láì ní ìrètí ọwọ́ àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà yóò wárìrì. Èmi yóò ṣe é fún wọn gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn, èmi yóò ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìgbékalẹ̀ wọn, nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé èmi ní Olúwa.”