15 Ó sọ fún mi pé, “Ṣé o rí báyìí, ọmọ ènìyàn? Ìwọ yóò tún rí ìríra tó ga jù èyí lọ.”
16 Ó mú mi wá sí ibi àgbàlá ilé Olúwa, lẹ́nu ọ̀nà tẹ́ḿpìlì Olúwa, wọn kọjú sí ìlà òòrùn, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún òòrùn ní apá ìlà òòrùn.
17 Ó sì wí fún mi, “Ṣé o ti rí èyí ọmọ ènìyàn? Ǹjẹ́ ohun kékéré ni fún ilé Júdà láti ṣe àwọn ohun ìríra tí wọn ń ṣe níbi yìí? Ṣé ó tún yẹ kí wọ́n fi ìwà ipá kún ilẹ̀ kí wọn sì máa mú mi bínú ní gbogbo ìgbà? Wò wọn bi wọn se n fi ẹ̀ka wọn sínú inú wọn.
18 Nítorí náà, ń o fi ìbínú bá wọn wí; n kò ní i dá wọn sí bẹ́ẹ̀ ni n kò sì ní fojú àánú wò wọ́n. Bí wọ́n tilẹ̀ ń pariwo sí mi létí, n kò ní fetí sí wọn.”