1 Lẹ́yìn ikú Ábímélékì, ọkùnrin kan láti ẹ̀yà Ísákárì tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́. Tólà ọmọ Púà, ọmọ Dódò, dìde láti gba Ísírẹ́lì sílẹ̀. Ní Sámírì tí ó wà ní òkè Éfúráímù ni ó gbé.
2 Ó ṣe àkóso Ísírẹ́lì ní ọdún mẹ́talélógún. Nígbà tí ó kú wọ́n sìn ín sí Sámírì.
3 Jáírì ti ẹ̀yà Gílíádì ni ó dìde lẹ́yìn rẹ̀, ó ṣàkóso Ísirẹ́lì ní ọdún méjìlélógún.
4 Àwọn ọgbọ̀n ọmọ tí ó ní gún ọgbọ̀n kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Wọ́n ṣe àkóso ọgbọ̀n ìlú ní Gílíádì, tí a pe orúkọ wọn ní Háfótì Jáírì títí di òní.
5 Nígbà tí Jáírì kú wọ́n sin ín sí Kámónì.
6 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì tún ṣe ohun tí ó burú lójú Olúwa. Wọ́n sin Báálì àti Áṣítórétù àti àwọn òrìṣà Árámù, òrìṣà Ṣídónì, òrìṣà Móábù, òrìṣà àwọn ará Ámónì àti òrìṣà àwọn ará Fílístínì. Nítorí àwọn ará Ísírẹ́lì kọ Olúwa sílẹ̀ tí wọn kò sì sìn-ín mọ́,
7 ó bínú sí wọn, ó fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn ará Fílístínì àti Ámónì láti jẹ ẹ́ ní ìyà.
8 Ní ọdún náà, wọ́n tú wọn ká wọ́n sì pọ́n wọn lójú. Fún ọdún méjìdínlógún ni wọ́n fi ni gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́li tí ó wà ní ìlà oòrùn odò Jọ́dánì ní ilẹ̀ àwọn ará Ámórì lára (èyí nì ní Gílíádì).
9 Àwọn ará Ámónì sì la odò Jọ́dánì kọjá láti bá Júdà, Bẹ́ńjámínì àti àwọn ará ilé Éfúráímù jagun: Ísírẹ́lì sì dojú kọ ìpọ́njú tó lágbára.
10 Nígbà tí èyí ti ṣẹlẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ké pe Olúwa wí pé, “Àwa ti ṣẹ̀ sí ọ, nítorí pé àwa ti kọ Ọlọ́run wa sílẹ̀, àwa sì ń sin Báálì.”
11 Olúwa sì dáhùn pé, “Ǹjẹ́ nígbà tí àwọn ará Éjíbítì, Ámórì, Ámónì, Fílístínì,
12 àwọn ará Sídónì, Ámélékì pẹ̀lú Móánì ni yín lára, tí ẹ sì ké pè mí fún ìrànlọ́wọ́, ǹjẹ́ èmi kò gbà yín sílẹ̀ kúrò ní ọwọ́ wọn?
13 Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ ẹ̀yin kọ̀ mí sílẹ̀ láti sin àwọn ọlọ́run mìíràn, torí ìdí èyí, èmi kì yóò sì tún gbà yín mọ́.
14 Ẹ lọ kí ẹ sì ké pe àwọn òrìṣà tí ẹ̀yin ti yàn fún ara yín. Jẹ́ kí wọn gbà yín sílẹ̀ ní àsìkò ìpọ́njú yín!”
15 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì dá Olúwa lóhùn pé, “Àwá ti ṣẹ̀, ṣe ohun tí ó bá fẹ́ pẹ̀lú wa, ṣùgbọ́n, jọ̀wọ́ gbà wá sílẹ̀ ná ní àsìkò yìí.”
16 Nígbà náà ni wọ́n kó gbogbo ọlọ́run àjèjì tí ó wà láàárin wọn kúrò wọ́n sì sin Olúwa nìkan, ọkàn rẹ̀ kò sì le gbàgbé ìrora Ísírẹ́lì mọ́.
17 Nígbà tí àwọn ará Ámónì kógun jọ ní Gílíádì láti bá Ísírẹ́lì jà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbárajọpọ̀ wọ́n sì tẹ̀dó ogun ní Mísípà.
18 Àwọn ìjòyè: aṣíwájú àwọn ará Gílíádì wí fún ará wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí yóò kọ́ sígun si àwọn ará Ámónì ni yóò jẹ́ orí fún gbogbo àwọn tí ń gbé ní Gílíádì.”