Onídájọ́ 2 BMY

Ańgẹ́lì Olúwa Ní Bókímù

1 Ní ọjọ́ kan ańgẹ́lì Olúwa dìde kúrò láti Gígálì lọ sí Bókímù ó sì wí pé, “Èmi mú un yín gòkè láti ilẹ̀ Éjíbítì wá, èmi sì ṣíwájú yín wá sí ilẹ̀ tí mo ti ṣèlérí láti fi fún àwọn baba ńlá yín. Èmi sì wí pé, ‘Èmi kì yóò yẹ májẹ̀mú mi pẹ̀lú yín.

2 Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ bá àwọn ènìyàn ilẹ̀ yí dá májẹ̀mú àlàáfíà, ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò wó pẹpẹ ibi ìsin òrìṣà wọn lulẹ̀.’ Ṣíbẹ̀ ẹ̀yin ṣe àìgbọ́ràn sími. Èéṣe tí ẹ̀yin fi ṣe èyí?

3 Ní báyìí, èmi wí fún un yín pé, èmi kì yóò lé àwọn ènìyàn jáde kúrò níwájú yín; ṣùgbọ́n wọn yóò jẹ́ ẹ̀gún ní ìhà yín, àwọn òrìṣà wọn yóò sì jẹ́ ìdánwò fún un yín.”

4 Bí ańgẹ́lì Olúwa sì ti sọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún àwọn ará Ísírẹ́lì tan, àwọn ènìyàn náà sì gbé ohùn wọn sókè wọ́n sì sunkún kíkorò,

5 wọ́n sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Bókímù (ibi tí àwọn ènìyàn ti sọkún). Wọ́n sì rúbọ sí Olúwa níbẹ̀.

Àìgbọ́ràn Àti Ìkùnà Ní Ogun.

6 Lẹ́yìn tí Jóṣúà ti tú àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì ká, àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì kọ̀ọ̀kan lọ sí ilẹ̀ tí a fi fún wọn láti lọ gbà á ní ìní wọn.

7 Àwọn ènìyàn náà sin Olúwa ní gbogbo ìgbà ayé Jóṣúà àti ní gbogbo ọjọ́ àwọn àgbààgbà tí ó wà lẹ́yìn ikú rẹ̀ tí wọ́n sì rí gbogbo iṣẹ́ ńlá tí Olúwa ṣe fún Ísírẹ́lì.

8 Jóṣúà ọmọ Núnì ìránṣẹ́ Olúwa kú ní ẹni àádọ́fà ọdún (110).

9 Wọ́n sì sìnkú rẹ̀ sí ààlà ilẹ̀ ìní rẹ̀ ní Tímínátì-Hérésì ní ilẹ̀ òkè Éfúráímù ní àríwá òkè Gásà.

10 Ní ìgbẹ̀yìn, gbogbo ìran náà sì kú; àwọn ìran tí ó tẹ̀lé wọn kò sì sin Olúwa nítorí wọn kò mọ Olúwa bẹ́ẹ̀ ni wọn kò mọ ohun tí Olúwa ṣe fún Ísírẹ́lì.

11 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe ohun tí ó burú níwájú Olúwa, wọ́n sì ń sin òrìṣà Bálímù.

12 Wọ́n kọ Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn sílẹ̀ ẹni tí ó mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì, wọ́n ń tọ àwọn òrìṣà lẹ́yìn, wọ́n sì ń sin àwọn oríṣìíriṣí òrìṣà àwọn ará ilẹ̀ ibi tí wọ́n ń gbé, wọ́n sì mú Olúwa bínú.

13 Nítorí tí wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀ àti nítorí pé wọ́n ń sin Báálì àti Ásítarótù.

14 Nínú ìbínú rẹ̀ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Olúwa fi wọ́n lé àwọn akónisìn lọ́wọ́ tí ó kó wọn ní ẹrú, tí ó sì bà wọ́n jẹ́. Ó sì tà wọ́n fún àwọn ọ̀ta wọn tí ó yí wọn ká àwọn ẹni tí wọn kò le dúró dè láti kọ ojú ìjà sí.

15 Nígbà-kí-ìgbà tí àwọn Ísírẹ́lì bá jáde lọ sí ojú ogun láti jà, ọwọ́ Olúwa sì wúwo ní ara wọn, àwọn ọ̀ta a sì borí wọn, àní gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún wọn, wọ́n sì wà nínú ìpọ́njú púpọ̀.

16 Olúwa gbé àwọn onídájọ́ (aṣíwájú tí ó ní agbára) dìde sí àwọn tí ó gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta wọn.

17 Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ wọn kò fi etí sí ti àwọn onídájọ́ wọn, ṣùgbọ́n wọ́n ṣe àgbérè, wọ́n ń sin òrìṣà. Wọn kò dàbí àwọn baba wọn, kíákíá ni wọ́n yípadà kúrò lọ́nà tí àwọn baba wọ́n ń tọ̀, ọ̀nà ìgbọràn sí àwọn òfin Olúwa.

18 Nígbà kí ìgbà tí Olúwa bá gbé onídàájọ́ dìde fún wọn, Olúwa máa ń wà pẹ̀lú onídàájọ́ náà, a sì gbà wọ́n kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀ta wọn ní ìwọ̀n ìgbà tí onídàájọ́ náà bá wà láàyè nítorí àánú Olúwa wà ní ara wọn, nígbà tí wọ́n bá ké ìrora lábẹ́ àwọn tí ń tẹrí wọn ba, tí sì ń fi ìyà jẹ wọ́n.

19 Ṣùgbọ́n ní gbàrà tí onídàájọ́ bá ti kú àwọn ènìyàn náà a sì tún padà sí ọ̀nà ìbàjẹ́ àní ju ti àwọn baba wọn lọ, wọn a tẹ̀lé òrìṣà, wọ́n ń sìn wọ́n, wọn a sì forí balẹ̀ fún wọn, wọ́n kọ̀ láti yàgò kúrò ní ọ̀nà ibi wọn àti agídí ọkàn wọn.

20 Ìbínú Olúwa yóò sì tún ru sí Ísírẹ́lì a sì wí pé, “Nítorí tí orílẹ̀-èdè yìí ti yẹ májẹ̀mu tí mo fi lélẹ̀ fún àwọn baba ńlá wọn, tí wọn kò sì fetí sí mi.

21 Èmi kì yóò lé ọ̀kankan nínú àwọn orílẹ̀-èdè tí Jóṣúà fi sílẹ̀ nígbà tí ó kú jáde.

22 Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀ èmi yóò lo àwọn orílẹ̀-èdè yìí láti fi dán Ísírẹ́lì wò, láti mọ̀ bóyá wọ́n yóò pa ọ̀nà Olúwa mọ́ àti pé bóyá wọn ó rìn nínú rẹ̀ bí àwọn baba ńlá wọn ti rìn.”

23 Nítorí náà Olúwa fi àwọn orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀ ní ilẹ̀ náà kò sì lé wọn jáde, tàbí kí ó jẹ́ kí àwọn Ísírẹ́lì pa wọ́n run.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21