Onídájọ́ 9 BMY

Àwọn Onídàájọ́

1 Ní ọjọ́ kan Ábímélékì ọmọ Jérúbù-Báálì lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin ìyá rẹ̀ ní Ṣékémù ó sì bá wọn sọ̀rọ̀ àti gbogbo àwọn ìbátan ìyá rẹ̀ wí pé,

2 “Ẹbi gbogbo àwọn ará Ṣékémù léèrè, ‘Èwo ló sàn fún un yín, ṣé kí gbogbo àwọn àádọ́rin ọmọ Jérú-Báálì jọba lórí yín ni tàbí kí ẹnìkan ṣoṣo ṣe àkóso yín?’ Ṣùgbọ́n ẹ rántí pé ẹran ara yín àti ẹ̀jẹ̀ yín ni èmi ń ṣe.”

3 Nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ sọ èyí ní etí àwọn ará Ṣékémù, ọkàn wọn fà sí àti tẹ̀lé Ábímélékì torí, wọ́n sọ wí pé, “Arákùnrin wa ní í ṣe.”

4 Wọ́n fún un ní àádọ́rin ṣékélì fàdákà láti ilé òrìṣà Bááli-Béritì, Ábímélékì fi owó náà gba àwọn jàǹdùkú àti aláìníláárí ènìyàn tí wọ́n sì di olùtẹ̀lé rẹ̀.

5 Ó kó wọn lọ sí ilé baba rẹ̀ ní Ófírà, níbẹ̀ ní orí òkúta kan ṣoṣo ni ó ti pa àádọ́rin nínú àwọn arákùnrin rẹ̀, àwọn Jérú-Báálì, ṣùgbọ́n Jótamù, àbíkẹ́yìn nínú àwọn ọmọ Jérúb-Báálì, bọ́ yọ nítorí pé ó sá pamọ́.

6 Gbogbo àwọn ará Ṣékémù àti àwọn ará Bẹti-Mílò pàdé pọ̀ ní ẹ̀bá igi óákù ní ibi òpó ní Ṣékémù láti fi Ábímélékì jọba.

7 Nígbà tí wọ́n sọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ yìí fún Jótamù, ó gun orí ṣóńṣó òkè Gérísímì lọ, ó sì ké lóhùn rara pé, “Ẹ tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin àgbààgbà Ṣékémù, kí Olúwa le tẹ́tí sí yín.

8 Ní ọjọ́ kan àwọn igi jáde lọ láti yan ọba fún ara wọn. Wọ́n pe igi Ólífì pé, ‘Wá ṣe ọba wa.’ ”

9 “Ṣùgbọ́n igi Ólífì dá wọn lóhùn pé, ‘Èmi yóò ha fi òróró mi sílẹ̀ èyí tí a ń lò láti fi ọ̀wọ̀ fún àwọn ọlọ́run àti ènìyàn kí èmi sì wá ṣolórí àwọn igi?’

10 “Àwọn igi sọ fún igi ọ̀pọ̀tọ́ pé, ‘Wá jọba ní orí wa.’

11 “Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀tọ́ dá wọn lóhùn pé, ‘Kí èmi fi èṣo mi tí ó dára tí ó sì dùn sílẹ̀ láti wá ṣolórí àwọn igi?’

12 “Àwọn igi sì tún sọ fún àjàrà pé, ‘Wá, kí o ṣe ọba wa.’

13 “Ṣùgbọ́n àjàrà dáhùn pé, ‘Ṣé kí èmi dẹ́kun àti máa so èṣo wáìnì mi èyí tí ó ń mú inú Ọlọ́run àti àwọn ènìyàn dùn láti máa ṣe olórí àwọn igi?’

14 “Ní ìparí gbogbo àwọn igi lọ bá igi ẹ̀gún wọ́n sì sọ fún un pé, ‘Wá kí ó ṣe ọba wa.’

15 “Igi ẹ̀gún dá àwọn igi lóhùn pé, ‘Bí lótítọ́ ni ẹ bá fẹ́ yàn mí ní ọba yín. Ẹ sá àṣálà sí abẹ́ ìbòji mi; ṣùgbọ́n tí kì í bá ṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí ìná jáde láti inú igi ẹ̀gún kí ó sì jó àwọn igi Kédárì àti ti Lẹ́bánónì run!’

16 “Báyìí tí ó bá jẹ́ pé ẹ̀yín ṣe ohun tí ó ní ọlá àti pẹ̀lú ẹ̀mí òtítọ́ ní fífi Ábímélékì jọba, tí ó bá ṣe pé ohun tí ó tọ́ ni ẹ ṣe sí Jérú-Báálì àti ìdílé rẹ̀, bí ẹ bá san ẹ̀san tó yẹ fún un.

17 Nítorí pé baba mi jà nítorí yín, ó fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu láti gbà yín sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Mídíánì;

18 ṣùgbọ́n lónìí ẹ̀yin ṣọ̀tẹ̀ sí ilé baba mi, ní orí òkúta kan ṣoṣo ni ẹ ti pa àwọn àádọ́rin ọmọ rẹ̀, ẹ̀yin sì ti fi Ábímélékì ọmọ ẹrú-bìnrin rẹ̀ jọba lórí àwọn ènìyàn Ṣékémù nítorí tí ó jẹ́ arákùnrin yín.

19 Bí ohun tí ẹ ṣe sí Jérú-Báálì àti ìdílé rẹ̀ bá jẹ́ ohun tí ó yẹ, tí ẹ sì ṣe òtítọ́ inú sí i, kí ẹ ní ayọ̀ nínú Ábímélékì kí òun náà sì ní ayọ̀ nínú yín.

20 Ṣùgbọ́n tí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí iná jó jáde wá láti ọ̀dọ̀ Ábímélékì kí ó sì jó yín run. Ẹ̀yin ará Ṣékémù àti ará Bétí-Mílò, kí iná pẹ̀lú jáde láti ọ̀dọ̀ yín wá ẹ̀yin ará Ṣékémù àti ará Bétí-Mílò kí ó sì jó Ábímélékì run.”

21 Lẹ́yìn tí Jótamù ti sọ èyí tan, ó sá àṣálà lọ sí Béérì, ó sì gbé níbẹ̀ nítorí ó bẹ̀rù arákùnrin rẹ̀ Ábímélékì.

22 Lẹ́yìn tí Ábímélékì ti ṣe àkóso Ísírẹ́lì fún ọdún mẹ́ta,

23 Ọlọ́run rán ẹ̀mí búburú sáàárin Ábímélékì àti àwọn ará Ṣékémù, àwọn ẹni tí ó hu ìwà ọ̀tẹ̀.

24 Ọlọ́run ṣe èyí láti gbẹ̀san àwọn ìwà búburú, àti ìtàjẹ̀ sílẹ̀ àwọn àádọ́rin (70) ọmọ Jérúbù-Báálì lára Ábímélékì arákùnrin wọn àti lára àwọn ènìyàn Ṣékémù, ẹni tí ó ràn án lọ́wọ́ láti pa àwọn arákùnrin rẹ̀.

25 Nítorí ìkórira tí wọ́n ni sí àwọn olórí, ni Ṣékémù dẹ àwọn ènìyàn sí àwọn orí òkè láti máa dá àwọn ènìyàn tó ń kọja lọ́nà, kí wọn sì máa jà wọ́n lólè, àwọn kan ló sọ èyí fún Ábímélékì.

26 Gáálì ọmọ Ébédì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ wá sí Ṣékémù, àwọn ará Ṣékémù sì gbàgbọ́ wọ́n sì fi inú tán wọn.

27 Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jáde lọ sí oko, wọ́n sì ṣa èṣo àjàrà wọn jọ, wọ́n fún èṣo àjàrà náà, wọ́n si ṣe àjọ̀dún nínú ilé òrìṣà wọn. Nígbà tí wọ́n ń jẹ tí wọ́n ń mu wọ́n fi Ábímélékì ré.

28 Gáálì ọmọ Ébédì dáhùn pé, “Ta ni Ábímélékì tàbí tani Ṣékémù tí àwa ó fi sìn ín? Ọmọ Jerubu-Báálì kọ́ ní ṣe tàbí Ṣébútì kọ́ ní igbá kejì rẹ̀? Ẹ má sin àwọn ará Hámórì baba àwọn ará Ṣékémù, Èéṣe tí a ó fi sin Ábímélékì?

29 Bí àwọn ènìyàn yìí bá wà ní abẹ́ ìsàkóso mi ni! Ẹ̀yin ó bọ́ àjàgà rẹ̀ kúrò ní ọrùn yín (Èmi yóò yọ Ábímélékì kúrò). Èmi ó ò wí fún Ábímélékì pé, ‘Kó gbogbo àwọn ogun rẹ jáde láti jà.’ ”

30 Nígbà tí Ṣébúlù, alákoṣo ìlú náà gbọ́ ohun tí Gáálì ọmọ Ébédì sọ, inú bí i gidigidi.

31 Ó ránṣẹ́ sí Ábímélékì pé, “Gáálì ọmọ Ébédì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ wá láti máa gbé ní Ṣékémù ṣùgbọ́n, wọ́n ń rú àwọn ènìyàn sókè láti sọ̀tẹ̀ sí ọ.

32 Wá ní òru kí ìwọ àti àwọn ogun rẹ sá pamọ́ dè wọ́n nínú igbó.

33 Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù bí oòrùn ti ń yọ ìwọ yóò wọ inú ìlú náà lọ láti bá a jà. Yóò sì ṣe nígbà tí Gáálì àti àwọn ogun rẹ̀ tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ bá jáde sí ọ láti bá ọ jà, ìwọ yóò ṣe ohunkóhun tí o bá fẹ́ sí wọn.”

34 Ábímélékì àti gbogbo àwọn ogun rẹ̀ sì jáde ní òru, wọ́n sì lúgọ (sápamọ́) sí ọ̀nà mẹ́rin yí Ṣékémù ká.

35 Gáálì ọmọ Ébédì jáde síta, ó sì dúró ní ẹnu ọ̀nà ibodè ìlú náà ní àkókò tí Ábímélékì àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jáde kúrò níbi tí wọn sá pamọ́ sí.

36 Nígbà tí Gáálì rí àwọn ènìyàn náà, ó sọ fún Ṣébúlù pé, “Wòó, àwọn ọkùnrin kan ń bọ̀ wá, láti orí àwọn òkè!”Ṣébúlù dá a lóhùn pé, “àṣìṣe lò ǹ ṣe oò ríi dáadáa, òjìji òkè ni ò ń pè ní àwọn ènìyàn.”

37 Gáálì ké ó ní, “Wòkè, àwọn ènìyàn ń tọ̀ wá bọ̀ láti agbede-méjì ilẹ̀ wá àti ẹ̀gbẹ́ kan n sì ń bọ̀ láti ìhà igi àwọn aláfọ̀ṣẹ tí ń jẹ́ óákù-Méónénímù.”

38 Nígbà náà ni Ṣébúlù dá a lóhùn pé, “Níbo ni ẹnu tí ó ń ṣe ni wà báyìí. Ṣe bí o wí pé, ‘Ta ni Ábímélékì tí àwa ó fi máa sìn ín?’ Àwọn ẹni tí ó gàn án kọ́ nìyí? Jáde lọ kí o sì bá wọn jà!”

39 Gáálì sì ṣíwájú àwọn ogun ará Ṣékémù lọ kọjú Ábímélékì láti bá wọn jagun.

40 Ábímélékì sì lé e, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ogun ṣubú wọ́n sì gbọgbẹ́ bí wọ́n ṣe ń sáá lọ, títí dé ẹnu ọ̀nà ibùdó ìlú náà.

41 Ábímélékì dúró sí Árúmà, nígbà tí Ṣébúlù lé Gáálì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ kúrò ni Ṣékémù, kò sì jẹ́ kí wọ́n gbé Ṣékémù mọ́.

42 Ní ọjọ́ kejì àwọn ará Ṣékémù sì jà lọ́ sí oko, ẹnìkan ló ṣe òfófó rẹ̀ fún Ábímélékì.

43 Ó kó àwọn ènìyàn rẹ̀, ó pín wọn sí ẹgbẹ́ mẹ́ta ó sì sá pamọ́ sí inú oko. Nígbà tí ó sì rí tí àwọn ènìyàn náà ń jáde kúrò nínú ìlú, ó dìde ó gbógun tì wọ́n.

44 Ábímélékì àti àwọn ọmọ ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sáré síwájú, wọ́n gba ẹnu ibodè ìlú náà, wọ́n sì dúró níbẹ̀. Àwọn ẹgbẹ́ méjì tókù sì sáré sí àwọn tó wà ní oko wọ́n sì gbógun tì wọ́n.

45 Ní gbogbo ọjọ́ náà ni Ábímélékì fi bá àwọn ará ìlú náà jà, ó sì ṣẹ́gun wọn, ó sì pa àwọn ènìyàn ìlú náà ó wó ìlú náà palẹ̀ pátapáta ó sì fọ́n iyọ̀ sí i.

46 Àwọn ènìyàn ilé ìṣọ́ Ṣékémù gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, wọ́n sá lọ fún ààbò sí inú ilé ìsọ́ agbára Ọlọ́run Bérítì (El-Bérítì).

47 Nígbà tí wọ́n sọ fún Ábímélékì pé àwọn ènìyàn ilé ìṣọ́ Ṣékémù kó ara wọn jọ pọ̀.

48 Òun àti gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gun òkè Sálímónì lọ. Ó gé àwọn ẹ̀ka díẹ̀ pẹ̀lú àáké, ó gbé àwọn ẹ̀ka wọ̀nyí sí èjìká rẹ̀. Ó sọ fún àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pé, “Ẹ ṣe ohun tí ẹ rí tí mo ń ṣe yìí ní kíákíá.”

49 Báyìí gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ gé àwọn ẹ̀ka igi wọn tẹ̀lé Ábímélékì. Wọ́n kó wọn ti ilé ìṣọ́ agbára níbi tí àwọn ènìyàn sá pamọ́ sí wọ́n sì fi iná síi pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà níbẹ̀. Gbogbo àwọn ènìyàn náà tí ó tó ẹgbẹ̀rún ènìyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin sì kú.

50 Ábímélékì tún lọ sí Tébésì, ó yí ìlú náà ká pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun, ó sì ṣẹ́gun rẹ̀.

51 Ilé ìṣọ́ kan tí ó ní agbára sì wà nínú ìlú náà. Gbogbo àwọn ènìyàn ìlú náà ọkùnrin àti obìnrin sá sínú ilé ìṣọ́ náà. Wọ́n ti ara wọn mọ́ ibẹ̀ wọ́n sì sá lọ sí inú àjà ilé ìṣọ́ náà.

52 Ábímélékì lọ sí ìṣàlẹ̀ ilé ìṣọ́ náà, ó sì ń bá a jà. Ṣùgbọ́n bí ó ti súnmọ́ ẹnu ọ̀nà ilé ìṣọ́ náà láti dáná sun ún,

53 obìnrin kan sọ ọmọ ọlọ lé e lórí, ó sì fọ́ ọ ní agbárí.

54 Ní ojú kan náà ni ó pe ẹni tí ó ru àpáta rẹ̀ pé, “Yára yọ idà rẹ kí o sì pa mí, kí wọn má ba à sọ pé, ‘Obìnrin ni ó pa á.’ ” Ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì fi ọ̀kọ̀ gún-un ó sì kú.

55 Nígbà tí àwọn ará Ísírẹ́lì rí i pé Ábímélékì kú, olúkúlùkù wọn padà sí ilé rẹ̀.

56 Báyìí ni Ọlọ́run san ẹ̀san ìwà búburú ti Ábímélékì hù sí baba rẹ̀ ní ti pípa tí ó pa, àwọn àádọ́rin (70) arákùnrin rẹ̀.

57 Ọlọ́run jẹ́ kí ìwà búburú àwọn ará Ṣékémù pẹ̀lú padà sí orí wọn. Ègún Jótamù ọmọ Jérú-Báálì pàápàá wá sí orí wọn.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21